You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
''Ìjọba ṣetàn láti káwọn ọmọ Nàìjíríà tó há sí Lebanon wálé látàrí bí Israel àti Lebanon ṣe ń ju àdó olóró sí ara wọn''
Ijọba apapọ ti bẹrẹ eto lati kawọn ọmọ orilẹede Naijiria to ha si Lebanon wale latari ogun to bẹ silẹ laarin Israel ati orilẹede naa.
Ajọ NEMA to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria lo fi ọrọ yii lede loju opo X rẹ lọsan ọjọ Ẹti.
Ajọ NEMA ṣalaye pe awọn to ba fẹ wale ni ijọba yoo ko o wale lati Lebanon.
Ajọ NEMA ṣalaye pe awọn to ba fẹ wale ni ijọba yoo ko o wale lati Lebanon.
Fun idi eyi, ijọba ti gbe igbimọ ẹlẹkajẹka kan dide eyi ti yoo maa sọ ohun to n ṣẹlẹ sawọn ọmọ Naijiria to wa ni orilẹede Lebanon.
Igbimọ naa si ni yoo tun ṣeto bawọn ọmọ Naijiria to ha si orilẹede naa yoo ṣe pada wale ni alaafia.
Ajọ NEMA lo n ṣamojuto eto naa eyi ti wọn ti bẹrẹ pẹlu kiko awọn ọmọ Naijiria to wa ni Lebanon jọ.
Lẹyin eyi ni wọn yoo bẹrẹ si ni maa ko wọn wale.
Ẹwẹ, olori awujọ awọn ọmọ Naijiria lorilẹede Lebanon sọ ipa ti olu ileeṣẹ Naijiria to wa ni Lebanon ko nipa koko awọn eeyan kuro lawọn agbegbe to lewu.
O ṣalaye wi pe ọmọ ko si ọmọ Naijira kankan ti o ti ku ninu ogun to n lọ lọwọ laarin Lebanon ati Israel.
Ni bayii, ijọba ti gbawọn ọmọ Naijiria to fẹ wale ni imọran lati bẹrẹ si maa lọ si olu ileeṣẹ Naijiria to wa niluu Beirut nibi ti ijọba yoo ti fi baalu ko wọn wa.