Mílíọ́nù méjìdínlógójì tọ́ọ̀nù oúnjẹ ló ń ṣòfò ní Naijiria lọ́dọdún – Àjọ EU
Ajọ European Union ti kede pe nnkan bii miliọnu mejidinlogoji tọọnu ounjẹ lo n ṣofo ni Naijiria lọdọdun, eyii to jẹ iye ounjẹ to n ṣofo to pọju ni Afrika.
Ijọba apapọ, ajọ EU ati ajọ United Nations Industrial Development Organisation ti wa ke si awọn ti ọrọ kan lati wa ọna lati fopin si irufẹ iwa bẹẹ.
Wọn ni ti ounjẹ ba n ṣofo, o n tumọ si pe omi, asiko ati okun ti wọn fi pese ounjẹ naa ti ṣofo niyẹn.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, eyii naa tun n ṣakoba fun ayipada oju ọjọ, bẹẹ lo ṣakoba fun igbiyanju awọn ajọ to n pariwo pe ki awọn eeyan ma fi ounjẹ ṣofo.
Ọrọ naa wa lara nnkan ti awọn aṣoju ajọ EU si Naijiria ati ECOWAS jiroro le lori lana ọjọ Aje.
Nigba to n sọrọ niluu Abuja lori idi ti awọn eeyan ko fi gbọdo maa fi ounjẹ ṣofo, Zissimos Vergos to jẹ igbakeji aṣoju EU si Naijiria ati ECOWAS sọ pe lọdun 2022 nikan, idaji biliọnu tọọnu kan ounjẹ lawọn eeyan fi ṣofo lagbaye, eyii to jẹ ida ogun gbogbo ounjẹ to wa fun awọn eeyan.
O ni "Eyii kii ṣe nipa fifi ounjẹ ṣofo nikan, o jẹ fifi anfani ti a ni ṣofo, eyi to jẹ anfani fun wa lati gbogun ti ebi."
Ọkunrun naa tẹnumọ pe fifi ounjẹ ṣofo wa lara nnkan to n ṣakoba fun awujọ, koda, idamẹwaa lo ko ninu awọn nnkan to n ba awujọ jẹ.
Vergos gboriyin fun ijọba Naijiria fun awọn ohun to n ṣe lati gbogun ti bi awọn eeyan ṣe n fi ounjẹ ṣofo.
Ọna mẹta lati dena fifi ounjẹ ṣofo ni Naijiria
Lẹyin naa lo kede ọna mẹta gboogi ti Naijiria fi le din fifi ounjẹ ṣofo ku.
Ohun akọkọ to sọ ni pe ijọba gbọdọ ṣatunṣe awọn opopona to wa lawọn igberiko.
Ekeji ki ijọba bẹrẹ fifi awọn ounjẹ to le bajẹ ṣe awọn ounjẹ mii ti wọn le ko pamọ, bii tomato inu agolo ati ẹgẹ ti wọn lọ.
Ẹkẹta gẹgẹ bii ọrọ rẹ ni pe ki ijọba bẹrẹ si n kọ awọn akẹkọọ nipa ewu to wa ninu ki wọn maa fi ounjẹ ṣofo.
O ni wọn gbọdọ bẹrẹ eto ẹkọ naa lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ titi de fasiti.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available