Ìdìtẹ̀gbàjọba: Ecowas kéde ìlú ò fararọ lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn Africa
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àjọ Economic Community of West African States (ECOWAS) ti kéde ìlú ò fararọ ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Africa.
Ààrẹ ECOWAS, Omar Touray ló kéde èyí níbi ìpàdé àjọ náà tó wáyé lórí ètò ààbò ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Afrika tó wáyé ní ìlú Abuja.
Ìpàdé ọ̀hún ni wọ́n pè látàrí bí ìdìtẹ̀gbàjọba ṣe ń wáyé ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.
Touray ní ìgbésẹ̀ kíkéde ìlú ò fararọ lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn Africa jẹ́ ojúnà láti ṣàtúnṣe ọjọ́ iwájú ìjọba àwaarawa àti ìnílò láti dókoòwò sí ẹ̀ka ètò ààbò ìwọ̀ oòrùn Afrika.
Ìkéde ìlú ò fararọ yìí lẹ́yìn tí ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé ní Niger, Burkina Faso, Mali àti Guinea, tó fi mọ́ ìdìtẹ̀gbàjọba tí kò kẹ́sẹ járí ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin tó wáyé lọ́jọ́ Àìkú.
Bákan náà ni àwọn ológun kan gbèrò láti gbàjọba ní Guinea-Bissau nínú oṣù tó kọjá, bí wọ́n ṣè gbìyànjú láti da ètò òṣèlú orílẹ̀ èdè náà rú.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available