Ẹgbẹ́ òsèlú Republican gba ilé asòfin kékeré mọ́ Democrats lọ́wọ́ ní Amerika

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ oṣelu Republicans ti gba iṣakoso ijoko ile 218 ti wọ̀n nilo lati di ipo ọmọ ile to pọjulọ mu ni ile aṣofin kekere.

Bio tilẹ jẹpe iye ọmọ ile ti ẹgbẹ oṣelu Republican fi ju Democrats lọ ko pọ rara, o ṣeeṣe ki wọn di aarẹ Biden lọwọ lati gbe awọn igbeṣẹ kọọkan.

Adari awọn aṣofin lẹgbẹ oṣelu Republican fi idunnu rẹ han pẹlu esi idibo naa.

Amo ẹgbẹ oṣelu Democrats ti di ipo adari ni ile igbimọ aṣofin, Senate.

Oṣu Kini, ọdun to n bọ ni Ile Igbimọ aṣofin tuntun naa yoo korajọ.

Ẹgbẹ oṣelu Republicans naa ni wọn lero wi pe wọn yoo jawe olubori ni ile igbimọ aṣofin kekere ati ile igbimọ aṣofin agba.

Ọṣẹ to kọja ni wọn ṣe idibo aarin saa lorilẹede Amerika.

Nibayii, ninu ọmọ ile asọfin 435, ni wọn aṣofin to to 218 si 223.

Bakan naa ni wọn ti dibo yan Kevin McCarty to jẹ adari ẹgbẹ oṣelu Republican ni ile igbimọ aṣofin kekere gẹgẹ bi ẹni ti yoo jẹ abẹnugan ile igbimọ aṣofin.

Mọ̀ sí i nípa ètò ìdìbò ilé ìgbìmò asòfin Amẹrika

aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ohun ti o gbodo mo nipa idibo Abenu Amerika.

Ni ọjọ kejo Oṣu kọkanla ,ọdun 2022, orilẹ-ede Amẹrika yoo ṣe ẹto idibo si awọn ilẹ igbimọ asofin mejeji ni ilu Amerika.  Awọn abajade  ẹto idibo naa ni yoo ni ipa ninu ọdun meji to ku ti  iṣe akoso Joe Biden.

 Eyi jẹ idibo si ile-igbimọ asofin,ati Ile Awọn Aṣoju sofin.

 Irú ìdìbò bẹ́ẹ̀ máa ń waye laarin ọ́dún méjì, isejoba ààrẹ Amẹrika .

 Ile-igbimọ   asofin ni o ma n ṣe awọn ofin orilẹ-ede naa ti Ile Awọn Aṣoju sofin ma un  jiroro lori awọn ofin, nigba ti awọn asoju sofin maa fọwọsi tabi fagile awọn ofin,ti wọn si ni agbara lati ṣe iwadii aarẹ orilẹ-ede Amẹrika.

Ilu kọkan ni orilẹ-ede Amẹrika ni aṣoju sofin meji,ti wọn a si lo Ọdun mẹfa.

Gbogbo ijọkọ ile igbimọ aṣọju sofin ni wọn yoo dibọ sii ati ida kan ninu meta ile igbimọ asọfin agba.

Ninu ẹto idibo yii ni idibo si ipo gomina ati awọn ijọba ibilẹ.

Awọn ẹgbẹ oṣelu Democrats lo ni ọpọlọpọ  ijoko ni awọn ile igbimọ aṣofin mejeeji lati ọdun meji sẹyin eyiti o ṣe iranlọwọ fun Aarẹ Joe Biden lati gba ifọwọsi awọn ofin ti o daba. 

Awọn abajade  ero awọn eniyan fihan pe ẹgbẹ ọselu Republican le gba ijoko to  poju ninu Ile igbimo  Aṣoju sofin, ṣugbọn o dabi pe Awọn egbe oselu Democrat yoo  padanu pupọ ninu awọn ijoko ile igbimo asofin.

 

aworan

Oríṣun àwòrán, others

Awọn aaye ti ariyanjiyan le wa?

 

 Ni ibẹrẹ odun 2022, awọn koko-ọrọ to pe fun  ijiroro ni ọrọ to nise lori iwa irufin,atipo ati gbigbẹ  igbesi aye irorun, eyiti yoo fa awọn ibo sinu  Ẹgbẹ Oloṣelu Republican.

 Ṣugbọn  iyipada  de ba ni Oṣu Karun ọdun yii, lẹhin ti Ile-ẹjọ giga fagile ofin iṣẹyun,eyiti o  bu si okiki ẹgbẹ Democrat,ti ẹgbẹ naa tun ṣe atilẹyin fun awọn obinrin  lati ṣẹyun.

 

aworan

Oríṣun àwòrán, JOEBIDEN/FACEBOOK

 Ipa wo ni abajade idibo naa yoo ni?

 Ti ẹgbẹ oṣelu Democrat  ba tẹsiwaju lati di pupọ ninu ijoko ile mu, Aarẹ Joe Biden yoo ni anfani lati tẹsiwaju  ninu awọn erongba rẹ lori akanṣe nipa iyipada oju-ọjọ,itesiwaju ẹto ilera ti ijọba, daabobo  ẹtọ awọn ti o fẹẹ ṣẹyun.

  Ti Ẹgbẹ Oloṣelu Republican ba gba pupọ ninu ijoko ọkan ninu ile igbimo asofin tabi ti aṣoju sofin awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ yoo ni aye lati fi opin si  awọn aba eto Aarẹ Joe Biden.

  Ati pe wọn le ṣe ofintoto iwadii awọn ọran labe isejoba Aare Biden papajulo  awọn iṣowo to waye  laarin ọmọ Aarẹ Biden ati China tabi bii orilẹ-ede Amẹrika ṣe yara ko awọn ologun kuro ni Afganistan.

  Ni ọna kanna,yoo nira fun  Aarẹ Joe Biden lati yan eeyan sipo papa julo ipo oloye agba eka eto idajọ.

aworan

Oríṣun àwòrán, donald trump/facebook

Ipá wo ni èyí yoo ni lórí eto ìdìbò ààrẹ 2024?

 

Eto idibo silẹ asofin orilẹ-ede Amẹ́ríkà yoo foju ẹniti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu Republican ninu eto idibo ọdun 2024.

Ti awọn oludije ti Trump  Aare Amerika ana ṣe atilẹyin fun ba kuna lati ni ipa ninu idibo naa, yoo ṣoro fun Ẹgbẹ Republican  lati fun ni aye lati tun du ipo aarẹ lẹẹkansi. 

Gomina Florida ati Texas, Ron DeSantis ati Greg Abbott nireti pe  ti awọn ba wọle elekeji wọn yoo tesiwaju lati dije du ipo aare ni orilẹ-ede Amerika.

Ti ẹgbẹ oṣelu Democrat ba tẹsiwaju lati di Michigan, Wisconsin ati Pennsylvania mu, iyẹn yoo mu ki iwuri pọ si lati rii pe Joe Biden tun dije du ipo aarẹ fun igba keji ninu eto  idibo ọdun 2024.