Iran ju àdó olóró sí iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà tó wà ní Iraq
Orílẹ̀ èdè Iran ti tún ṣe ìkọlù ọ̀tun sí Iraq ní ìdáhùn sí ogun tó ń wáyé láàárín orílẹ̀ èdè náà àti Amẹ́ríkà pẹ̀lú Israel.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹta ni Iran tún ṣe ìkọlù sí iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà tó wà ní Green Zone.
Iléeṣẹ́ ìròyìn AFP ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò sọ pé dúróònù mẹ́ta àti rọ́kẹ̀tì mẹ́rin ni Iran jus í iléeṣẹ́ náà àmọ́ ó dájú pé ọ̀kan lára àwọn àdó olóró náà balẹ̀ sínú iléeṣẹ́ náà.
Ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ sọ fún Reuters pé òun rí dúróònù mẹ́ta tó ń fò wọnú iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà náà tí àwọn ọmọ ogun Iraq sì mú méjì balẹ̀ nínú wọn.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Iraq sọ fún AFP pé ìkọlù yìí ni èyí tó lágbára jù tí Iran máa ṣe sí Iraq láti ìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀.
Ní ọjọ́ Ajé ni Iran ti kọ́kọ́ ju àdó olóró sí ilé ìtura kan ní Baghdad ní agbègbè tó jẹ́ pé àwọn iléeṣẹ́ ìjọba àti iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè wà.
Láti ìgbà tí ogun ti Amẹ́ríkà àti Israel ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbógunti Iran, iléeṣẹ́ ológun Iran ti ju àdó olóró tó lé ní 1,900 sí United Arab Emirates, UAE.
Àti ìgbà náà ni Iran ti ń ṣe ìkọlù sí àwọn iléeṣẹ́ ètò ìrìnnà àti epo UAE èyí tó ti ṣokùnfà ṣíṣe ìdádúró ètò irìnnà òfurufú fún ìgbà kan ná ní orílẹ̀ èdèlẹ́yìn tí àdó olóró ṣokùnfà ìjàmbá iná ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún.
Ní ọjọ́ Ajé kan náà ni àdó olóró tó balẹ̀ sórí ọkọ̀ kan ní olú ìlú UAE, Abu Dhabi ṣekúpa ọmọ Palestine kan.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkọlù ni Iran ti ṣe sí pápákọ̀ òfurufú Dubai láti ìgbà tí ogun Amẹ́ríkà/Israel àti Iran ti bẹ̀rẹ̀ ní oṣù Kejì èyí tó ti ṣokùnfà ọ̀pọ̀ ìdàrúdàpọ̀ ní Middle East.
UAE ní àwọn gbàgbọ́ pé wọ́n wọ́ àwọn wọnú ogun náà lọ́nà àìtọ́ èyí tí wọ́n gbàgbọ́ pé ó jẹ́ ojúnà láti le jẹ́ kí Amẹ́ríkà tètè fi òpin sí ogun náà.
Akọ̀ròyìn BBC ní UAE, Azadeh Moshiri sọ pé níṣe ni àwọn èèyàn ń kọminú lórí ohun tó máa jẹ ipa àwọn ìkọlù yìí lórí orílẹ̀ ède náà lẹ́yìn tí ogun bá parí.
Bákan náà ni iléeṣẹ́ ológun Qatar sọ pé àdó olóró mísáìlì mẹ́rìnlá ni Iran jù sí orílẹ̀ èdè náà lọ́jọ́ Ajé, tí àwọn sì rí mẹ́tàlá rọ̀ dànù nínú wọn àmọ́ tí wọ́n ní ẹyọ̀kan yòókù balẹ̀ sí agbègbè tí kò sí àwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀.
Iran ti ṣèkìlọ̀ láti ṣe ìkọlù sáwọn orílẹ̀ èdè Middle East tí Amẹ́ríkà bá gbe ogun tì í
Ní oṣù Kejì ni olórí orílẹ̀ èdè Iran tó ti jáde láyé, Ayatollahi Ali Khamenei ti ṣèkìlọ̀ pé tí Amẹ́ríkà bá ṣe ìkọlù sí àwọn le ṣokùnfà kí ogun bẹ̀rẹ̀ ní ẹkùn náà.
Khamenei sọ ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kejì pé ó yẹ kí Amẹ́ríkà mọ̀ pé bí òhun bá bẹ̀rẹ̀ ogun pẹ̀lú Iran báyìí, ó máa jẹ́ ogun ní ẹkùn Middle East.
Ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ ní Iran ló ti ṣáájú ṣèkìlọ̀ pé ó ṣeéṣe kí ètò ìrìnnà gba orí omi àti ohun àmúṣagbára faragbá ní Strait of Hormuz tí ogun bá bẹ̀rẹ̀ ní ékùn náà.
Iran ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àwọn ìkọlù tó lágbára sáwọn orílẹ̀ èdè tí Amẹ́ríkà ní ibùdó àwọn ológun ní ẹkùn Middle East tó fi mọ́ Qatar, Bahrain, Jordan, UAE, àti Kuwait.
Iran ti gbìyànjú láti ṣe ìkọlù sáwọn ibùdó Amẹ́ríkà tó wà ní àwọn orílẹ̀ èdè Middle East tẹ̀lẹ̀ rí tó fi mọ́ Al-Udeid tó wà ní Qatar nígbà tí Amẹ́ríkà ṣèkọlù sí ní ọdún tó kọjá.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available