Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn OAU ṣubú lulẹ̀ lásìkò tó ń múra ìdánwò, jáde láyé
Oríṣun àwòrán, @OAUniversity
Akẹkọọ imọ iṣẹgun kan ni fasiti Obafemi Awolowo to wa niluu Ile Ife, nipinlẹ Osun, Adewole Emmanuel ti jade laye lẹyin to ṣadede ṣubu lulẹ.
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ti ọmọ ọdun mejidinlogun kan to n kẹkọọ imọ iṣẹgun nile ẹkọ kan naa, Timilehin Toromade jade laye loju orun rẹ lọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2026 yii.
Ni ti akẹkọọ to ṣẹṣẹ ku yii, iroyin ni niṣe lo ṣadede ṣubu lulẹ lasiko to n mura lati ṣe ọkan lara awọn idanwo rẹ.
Ipele kẹrin ni akẹkọọ naa wa ṣaaju iṣẹ ọhun.
Ninu atẹjade kan ti awọn adari ẹgbẹ aṣoju akẹkọọ ile ẹkọ ọhun fi lede, wọn ni iṣẹlẹ iku akẹkọọ naa ba ọkan awọn jẹ.
Atẹjade naa sọ pe "Lana ni iṣẹlẹ ibanujẹ waye lagbo wa lẹyin ọkan ninu wa ṣadede ṣubu lulẹ, to si jade laye lasiko to yẹ ko bẹrẹ idanwo afẹnuṣe kan.
"Bo tilẹ jẹ pe awọn oniṣegun gbiyanju lati doola rẹ lẹyin to ṣubu lulẹ, o ṣeni laanu pe wọn sọ fun wa pe o ti fi aye silẹ lẹyin waka diẹ lẹyin naa.
"Iṣẹlẹ yii jẹ eyii ti a ko lero tẹlẹ, o si mi gbogbo inu ọgba ile ẹkọ wa titi, eyii to n ṣapẹrẹ pe ile aye ko lọ titi.
"A ba gbogbo awọn mọlẹbi atawọn ọrẹ oloogbe naa kẹdun. A si gbadura pe ki Eledua tu wọn ninu."
Ẹgbẹ akẹkọọ ọhun tun sọ pe iṣẹlẹ naa n fi han pe kii ṣe wahala kekere lawọn akẹkọọ n la kọja ninu ẹkọ wọn.
Wọn ni bo tilẹ jẹ pe awọn akẹkọọ n lakaka lati ṣaṣeyọri ninu ẹkọ wọn, wọn ko gbọdọ fi ilera ara wọn ṣere rara.
Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn akẹkọọ imọ isẹgun ninu atẹjade miran fidi iroyin naa mulẹ, wọn si ba awọn mọlẹbi oloogbe ọhun kẹdun.
Wọn juwe rẹ gẹgẹ bii ẹni to ni ọjọ ọla rere amọ ti iṣẹlẹ ọhun ti ge ẹmi rẹ kuru.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available