Wíwẹ̀ ní àárọ̀ tàbí alẹ́: Èwo ló dára jùlọ?
Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
- Author, Jasmin Fox-Skelly
- Role, BBC Future
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Fún ọ̀pọ̀ èèyàn, ìbéèrè tó rújú, tí wọ́n ń wá ìdáhùn sí ni pé èwo ló dára jùlọ níní ìwẹ̀ òwúrọ̀ àti ti alẹ́?
Àwọn míì ti ẹ̀ wà tó gbàgbọ́ pé kò yẹ láti máa wẹ̀ ní ojoojúmọ́.
Àmọ́ gbogbo yòówù tí o bá gbàgbọ́ lé lórí, èyíkéyìí tí o bá ń ṣe nínú rẹ̀ ló ní ipa lórí ìlera rẹ.
Fún ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn, ohun tí wọ́n máa ń kọ́kọ́ ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá jí ni láti bọ́ sí balùwẹ̀, kí wọ́n ṣá kànìnkànìn.
Àwọn tí wọ́n máa ń wẹ̀ ní àárọ̀ gbàgbọ́ pé dída omi sórí ní balùwẹ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá máa ń jẹ́ kí ara wọn jí pépé láti kojú iṣẹ́ oòjọ́ wọn.
Nígbà tí àwọn tó máa ń wẹ̀ ní alẹ́ sọ pé wíwẹ̀ kí àwọn tó bọ́ sórí ìbùsùn máa ń ṣe ìrànwọ́ fún wọn láti wẹ gbogbo àwọn ìdọ̀tí ara dànù, tí yóò sì jẹ́ kí wọ́n sùn dáadáa.
Èwo ló dára jùlọ níní ìwẹ̀ àárọ̀ àti alẹ́ lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì?
Gbígbé pẹ̀lú àwọn kòkòrò àìfojúrí
Ti a kò bá wẹ́ kí a tó sùn ní alẹ́, àwọn kòkòrò àìfojúrí máa ti ara èèyàn bọ́ sí orí ìbùsùn àti ìrọ̀rí tí èèyàn bá lò.
Èyí tó máa dàpọ̀ mọ́ àwọn sẹ́ẹ̀lì tó wà lára èèyàn.
Tí a bá ṣe àyẹ̀wò àwọ̀ ara lábẹ́ ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣe ìwádìí kòkòrò àìfojúrí, ó lé ní àwọn kòkòrò àìfojúrí láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sí mílíọ̀nù kan ló ń gbé nínú àwọ̀ èèyàn.
Àwọn òróró tó máa ń jáde lára ẹni nígbà tí èèyàn bá ń làágùn ni wọ́n fi ń ṣe oúnjẹ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àágùn fúnra rẹ̀ kìí rùn, àwọn ohun tí wọ́n máa jáde láti ara bíi kòkòrò staphylococcus máa ń rùn.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
A lè sọ pé kí èèyàn wẹ̀ ní alẹ́ kó tó sùn ló dára jùlọ ṣùgbọ́n ó ṣòro láti sọ pé ó jẹ́ òótọ́.
Onímọ̀ nípa biology ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Leicester ní UK, Primrose Freestone sọ pé lóòótọ̀ ni èèyàn máa sùn pẹ̀lú ara mímọ́ tó bá wẹ̀ kí ó tó sùn àmọ́ èèyàn ṣì máa làágùn láàárín òru.
Freestone fi kun pé kódà lásìkò òtútù, èèyàn ṣì máa ń làágùn bíi ìdajì lítà lásìkò tí èèyàn bá ń sùn nítorí ara máa ń da àwọn sẹ́ẹ̀lì tó tó ẹgbẹ̀rún àádọ́ta nígbà tí èèyàn bá ń sùn.
"Kódà bí èèyàn bá wẹ̀ kí ó tó sùn, nítorí ara máa ń ṣe àgbékalẹ̀ àwọn kòkòrò tó le jẹ́ kí èèyàn rùn tí èèyàn bá jí ní òwúrọ̀," Freestone sọ.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun tí ìwẹ̀ alẹ́ fi máa ń dára ni tí èèyàn bá ń máa ń fọ aṣọ iìbùsùn rẹ̀ lóòrèkóòrè nítorí àwọn kòkòrò àìfojúrí lè wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tí ẹ̀yà ara bá dúró dáadáa ní àǹfààní láti má nì í àìlera kankan látara àwọn kòkòrò àìfojúrí yìí, ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rin àwọn tó bá ní ásímà le ti ibẹ̀ ní àìlera.
Fífa àwọn ìdọ̀tí bíi Aspergillus fumigatus le fa àwọn àìsàn ọ̀nà ọ̀fun fún àwọn èèyàn tó bá ní ikọ́ ife àti àwọn àìsàn ọkàn míì.
"Fífọ aṣọ bẹ́ẹ̀dì lóòrèkóòrè ṣe pàtàkì ju wíwẹ̀ ní alẹ́ lọ," Holly Wilkinson," ọ̀jọ̀gbọ́n nípa egbò ní University of Hull ní UK sọ.
"Nítorí bí o bá ń wẹ̀ ní alẹ́ tí o ò bá fọ aṣọ ìbùsùn fún oṣù kan, àwọn kòkòrò àìfojúrí máa pọ̀ níbẹ̀, ó sì léwu fún ìlera."
Àwọn àǹfààní tó wà nínú oorun
Àwọn tó máa ń wẹ̀ lálẹ́ sọ pé ó máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sùn dáadáa tí ọ̀pọ̀ sì gbà pé bẹ́ẹ̀ ni.
Ìwádìí kan táwọn onímọ̀ ìlera ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wíwẹ omi gbígbónà fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá tó bá ku bíi wákàtí kan sí méjì máa ń tètè sùn ju àwọn tí kìí wẹ̀ lọ.
Pẹ̀lú àwọn nǹkan tí a ti sọ yìí, kí wá ni ìdáhùn sí ìbéèrè pé èwo ló dára jùlọ nínú ìwẹ̀ àárọ̀ tàbí alẹ́?
Freestone mú ìwẹ̀ àárọ̀ nítorí èèyàn máa ní àǹfààní láti fọ gbogbo àwọn àágùn àti ìdọ̀tí alẹ́ nù, tí èèyàn yóò sì bẹ̀rẹ̀ oòjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ara mímọ́.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àmọ́ ṣá, èyí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ipa kankan lórí ìlera ẹni; ó kàn dá lé lórí bí èèyàn bá ṣe fẹ́ kí ara òun mọ́ sí yálà ní òwúrọ̀ tàbí alẹ́.
"Tí èèyàn bá pinnu láti máa wẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́, ìgbà tó jẹ́ kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú rẹ̀," Wilkinson sọ.
"Níwọ̀n ìgbà tí ó ba ń fọ àwọn ibi tó ṣe pàtàkì lára lójúmọ́, wíwẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mejì láàárín ọ̀sẹ̀ dára láti gbé ìgbé ayé ìlera.
"Ó tún dá lórí irú iṣẹ́ tí èèyàn ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó bá jẹ́ àgbẹ̀ máa nílò láti wẹ̀ ní kété tó bá padà sílé lẹ́yìn iṣẹ́.
"Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ ni fífọ àwọn aṣọ ìbùsùn ju ohunkóhun lọ," Wilkinson ṣàlàyé.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available