Africa in Pictures: Àwọn àwòràn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti ilẹ̀ Afirika

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọbinrin akẹkọ mẹta ni orilẹede Sierria Leone to n ti ile iwe bọ, sa si abẹ́ aburada kansoso lasiko ti ojo n rọ. Eyi tumọ̀ si pe bi ifẹ ba wa, yara kekere gba ọpọ eeyan, inu ko gba, ni aaye ko gba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọdọọdun ni awọn adan maa n rababa yika oju ọdun nilu London, lati fo pada wa si ilẹ Afrika. Aworan yii lo si n fi ye wa pe oju ọrun to ẹyẹ fo lai fi apa kan ara wọn

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Iya ati ọmọ lo tu jade ni Khartoum, lorilẹede Sudan lati se iwọde tako ijọba ologun. Eyi tumọ si pe kaka ki ẹlulu ma dun ọbẹ, tapa titan rẹ ni yoo run si

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Inu ẹni kii dun, ka pa mọra. Sugbọn ere itage alafi orin kọ ni obinrin yii n se ni orilẹede Tunisia

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ero ree lode lasiko ti akọrin adulawọ kan, Aya Nakamura bọ sori itage lati kọrin lasiko ajọdun orin lorilẹede South France. Ero yii ti pọju

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Haa, awọn obinrin lo n luwẹ bii ẹja yii, ohun ti ọkunrin lee se, awọn obinrin naa le se e. orilẹede South Korea ni idije iwẹ lilu lagbaye naa ti n lọ lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Agbara ju agbara lọ, ọgbọn ju ọgbọn lọ. Eeyan kan ree to n dẹgbẹ lori okun lai si lori ọkọ oju omi, Huu, nkan n bẹ

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọlọrun ma jẹ ki itan yii fa ya, ki lo le to eyi. Anice Badri ọmọ orilẹede Tunisia ree to ya itan de agbari

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ara meeriri ree o. Okuta posi kan ree ti wọ̀n ya aworan si lara eyi ti wọn se awari rẹ nilu Cairo lorilẹede Egypt lọjọ Satide