You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
IlorinDurbar: Emir Sulu-Gambari léwájú àwọn èèkàn ẹlẹ́ṣin níbi àjọ̀dún Dubar nílú Ilọrin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Ayẹyẹ durba ilu Ilọrin waye loni pẹlu oniruru ilu, ijo ati ifọn.
Gẹgẹ bi ẹ ti ṣe mọ pe ohun kan ti kii gbẹyin nibi ajọdun durba ni ẹṣin gigun; eyi naa ko si gbẹyin nibi ajọdun Dubar ilu Ilọrin.
Lara awọn to peju sibi ajọdun naa ni Waziri ilu Ilọrin to tun jẹ aarẹ ile aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnetọ Bukọla Saraki.
Bakan naa ni olori ile aṣofin ipinlẹ Kwara, họnọrebu Ali Ahmad pẹlu wa nibẹ.
Lasiko ajọdun Dubar ilu Ilọrin ti ọdun yii, Emir ti ilu Ilọrin, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari lo lewaju awọn ẹlẹṣin ti ko din ni ẹẹdẹgbẹta pẹlu ṣin ti wọn ṣe lọṣọ ati lọjọ loriṣiriṣi lati ṣe ajọyọ ajọdun naa.