Ẹsa ninu aworan Afrika: 9-15, ose kẹta ọdun 2018

Ẹsa ninu awọn aworan to rẹwa ju l'Afrika ati aworan awọn ara Afrika nibomiran lagbaye ninu ọse yii.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ọkọ yii yatọ ni adugbo itan Bo Kaap nigboro Cape Town. Adugbo naa jẹ ibudo itan aṣa Malay nigboro Cape Town, osi jẹ ibudo mọṣalasi akọkọ ni orilẹede South Africa eleyi ti awọn ajeji kọ lọdun 1884 , gẹgẹ bi ileese iroyin EPA ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọkọ-akẹru yii da bii ẹni pe ọkan rẹ balẹ lẹyin igba ti agba gbe danu nilu Isinya, to to ogoji mẹli si olu ilu Kenya, Nairobi...

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Omi sọ ọna marose ilu naa di odo..

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Sugbọn awọn ọmọde wọn yii saasala kuro nibi ojo naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọmọkunrin kan ni orilẹede olu ilu orilẹede Senegal, Dakar, da bi ẹni to n ṣọra fun awọn eye kan ti wọn kọja lọ l'Ọjọru (Wednesday).

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, l'ọjọ Abamẹta, awọn eeyan ṣe iwọde l'awọn oju opoponaa igboro Floreence ni orilẹede Italy lati fi ẹhonu han lori pipa ọmọ orilẹede Senegal kan to n taja, Idy Diene.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, L'ọjọ kan naa, awọ eeyan ni orilẹede Tunisia ṣe iwọde lati ja fun ẹtọ awọn obirin nibi didọgba ninu ogun pinpin.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, L'orilẹede Mali, awọn Fulani yii n ṣe iwọde ni olu ilu orilẹede naa, Bamako, l'Ọjọbọ (Thursday) lori ikọlu laarin awọn daran-daran Fulani ati awọn agbẹ oloko ni aringungun Naijiria.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Darandaran yii n dari awọn ẹran rẹ lode ilu Mdhila, ọkan lara awọn ibuwa nnkan alumọni ni orilẹede naa , nibi tawọn oṣiṣẹ ti pada s'ẹnu iṣẹ lẹyin igba ti wọn da'ṣẹlẹ fun oṣu kan.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, L'ọjọ kannaa , Rebecca Palai n ba dokita kan sọrọ lori fonu nigba to n gba ogun lati ẹrọ ifunnilogun kan. Ẹrọ afunnilogun naa maa n fun awọn alaisan ti aisan wọn kii gb'ogun bọrọ ni anfani ati gba ogun laarin isẹju mẹta-mẹta, nigboro Alexandra, lorilẹede South Africa.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, L'ọjọ Aje (Monday), gbajugbaja agbegi-lere Kenya, Edward Njenga (lapa ọtun), ti wọn bi l'ọdun 1922, o n tun ere okuta rẹ ti wọn pe ni Women's Guild Member ṣe pẹlu atilẹyin ọmọ-ọmọ rẹ, ti orukọ rẹ naa n jẹ Edward Njenga, ni ileese rẹ ni Nairobi.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọkunrin kan n wo awọn iwe tita ninu awọn apoti ti wọn lo lati ko ohun ija pamọ tẹlẹ nigba ogun abẹle Libya ni igboro Misrata to wa ni Libya l'ọjọ Iṣẹgun (Tuesday).

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, L'ọjọ kan naa , awọn ọmọ orilẹede Libya yii n s'afihan aṣọ aṣa wọn lọjọ ayajọ aṣọ ibilẹ Libya ni olu ilu wọn, Tripoli.

Awọn aworan yii wa lat'ọdọ AFP, Reuters, EPA ati Getty Images