Ọmọ Nàìjíríà kan, ọmọ Ghana méjì àtàwọn orílẹ̀ède 129 míì fara gbọgbẹ́ nínú ìkọlù àdó olóró Iran tó ti gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà ní UAE

Aworan ibugbamu

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ileeṣẹ̀ eto abo lorilẹede United Arab Emirab, UAE ti kede rẹ pe ọmọ orilẹede Naijiria kan wa lara awọn eeyan mọkanlelaadoje ti wọn ti farapa ninu awọn ado oloro ti Iran ju si orilẹede naa.

Atẹjade naa yannana rẹ pe awọn ọmọ orilẹede UAE, Egypt, Sudan, Ethiopia, Philippines, Pakistan, Iran, India, Bangladesh, Sri Lanka, Azerbaijan, Yemen, Uganda, Eritrea, Lebanon, Afghanistan, Bahrain, Comoros, Türkiye, Iraq, Nepal, Nigeria, Oman, Jordan, Palestine, Ghana ati Indonesia wa lara awọn ọmọ orilẹede to fi ara pa ninu ikọlu ado oloro naa lati igba ti ogun ti bẹrẹ laari US-Israel ati Iran.

Awọn alaṣẹ orilẹede UAE ṣalaye siwaju sii pe awọn ado oloro to ti din diẹ ni ẹgbẹrun meji ninu eyi ti 268 ninu rẹ ẹya Ballistic missiles, marundinlogun rẹ jẹ ẹya Cruise missiles ti ẹgbẹrun kan o leẹẹdẹgbẹta ati mẹrinla (1514) ṣẹ ẹya ado oloro UAVs ni Iran ti yin ranṣẹ si orilẹede naa ṣugbọn ti awọn ti fẹ ọpọlọpọ rẹ danu loju ofurufu.

"Ikọlu wọnyii lo ṣokunfa iku eeyan mẹfa ti wọn jẹ ọmọ orilẹede Emirati, Pakistan, Nepal ati Bangladesh…"

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ki lorilẹede Naijiria n ṣe lori awọn ọmọ Naijiria to wa ni agbegbe ilẹ Larubawa?

Nibayii naa, ileeṣẹ ọrọ okeere ni Naijiria ti fi awọn nọmba ibanisọrọ kan sita fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria to lawọn agbegbe ilẹ Larubawa ti rukerudo ti n ṣẹlẹ bayii le pe si fun iranlọwọ lasiko yii.

Ninu atẹjade kan to fi sita, ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere lorilẹede rọ 'awọn ọmọ NAijiria ti ikọlu n waye lagbegbe wọn lati kan si awọn nọmba naa.

Awọ̀n nọmba yii ni wọn jẹ ti awọn ti ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria lawọn orilẹede bii Iran Israel, UAE, Kuwait, Qatar, Lebanon, Saudi Arabia ati Jordan.

Aworan atẹjade ti ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere ni Naijiria fi sita pẹlu awọn nọmba ibanisọrọ naa.

Oríṣun àwòrán, Ministry of Foreign Affairs, Nigeria

Orilẹede Ghana fariga lori ọmọ orilẹede rẹ meji ti ado oloro ba ni UAE

Awọn ọmọ orilẹede Ghana meji naa wa ninu awọn to ti fara gbọgbẹ ado oloro ti Iran n ju si orilẹede UAE lati igba ti ogun naa ti bẹrẹ.

Orilẹede naa ti koro oju si ado oloro abẹyẹfo to kọlu papakọ ofurufu Dubai ninu eyi ti meji ninu ọmọ orilẹede naa ti fara pa.

Gẹgẹ bii awọn alaṣẹ lorilẹede Ghana ṣe sọ, ohun pataki to jẹ ijọba Ghana logun ju ni dida abo bo ẹmi ati dukia awọn ọmọ orilẹede naa nibikibi ti wọn le wa lagbaye.

"Ijọba Ghana kọminu lori iṣẹlẹ to n dunkoko mọ ẹmi awọn araalu ati dukia wọn. Irufẹ iṣẹlẹ yii ma n dunkoko mọ ẹmi, ti a si nilo lati doola ẹmi awọn eeyan wa kaakiri,' atẹjade naa ṣalaye.

Iroyin nipa iṣẹlẹ naa kan awọn alaṣẹ orilẹede Ghana leti pe nibi ibugbamu ado oloro to waye ni Dubai ni ọjọ Isẹgun, ni wọn ti fara gbọgbẹ.

Aṣoju Ghana ni UAE lewaju awọn ikọ to ṣe abẹwo si awọn eeyan to farapa ni ile iwosan ti wọn ti n gba itọju.

Awọn alaṣẹ ni kii ṣe pe wọn farapa pupọ, ati pe laipẹ ni wọn yoo gba ilera pipe.

Aworan atẹjade ti ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere ni Ghana fi sita lori ẹhonu rẹ nipa ikọlu ado oloro to ba awọn ọmọ orilẹede rẹ meji.

Oríṣun àwòrán, Ghana MFA

Lati igba ti ogun ti bẹrẹ laarin Israel, Amẹrika ati Iran ni awọn orilẹede Afrika ti n kesi awọn eeyan ti ọrọ kan pe ki wọn bọwọ fun ofin agbaye, ki si wọn doola ẹmi awọn eeyan to n pe fun alaafia.

Ni ibẹrẹ oṣu yii ni Ijọba ilẹ Amẹrika ati orilẹede Israel pawọ pọ lati ju ado oloro si Iran.

Awọn aworan ti BBC foju ri ṣafihan bi eefin ṣe n ru laarin ilu Tehran, to jẹ olu ilu orilẹede Iran.

Lẹyin ikọlu naa ni Aarẹ Donald Trump sọ pe afojusun Washington ni lati dena ikọlu eyikeyi to le waye lati ọwọ Iran.

Ko pẹ si igba naa ni awọn ọmọ ogun orílẹ ede Iran sọ pe awọn ti ṣekọlu si oríko ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi ti ilẹ Amẹríka to wa ní Bahrain.

Wọn ni ìgbesẹ naa waye lati gbẹsan ikọlu tí Amẹríka ati Israel pawọpọ̀ ṣe sí orílẹ ede wọn.

Ileeṣẹ ologun UAE ti w ani idgbi ni awọn wa lati doola ẹmi ati dukia awọn eeyan to w ani agbegbe UAE