Wo orílẹ̀èdè márùn-ún tí inú àwọn èèyàn rẹ̀ dùn jùlọ lágbàáyé lọ́dún 2026

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Fún ọdún pípẹ́ ni àwọn orílẹ̀ èdè Nordic fi wà nípò àwọn orílẹ̀ èdè tí inú èèyàn ti ń dùn jùlọ ní àgbáyé, àyípadà ti ń dé báyìí.

Fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, orílẹ̀ èdè kan láti ẹkùn Latin America wọ ipò kẹrin orílẹ̀ èdè tí inú èèyàn ti ń dùn jùlọ ní àgbáyé.

Orílẹ̀ èdè Costa Rica ló ń fi ọdọọdún léwájú bí ó ṣe fò láti ipò kẹtàlélógún tó wà ní ọdún 2023 sí ipò kẹrin lọ́dún 2026.

Ìjábọ̀ náà, tí àjọ Oxford Health Research Institute pẹ̀lú àjọṣepọ̀ United Nations Sustainable Development Goals máa ń gbé jáde ní ọdọọdún, máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò ètò ọrọ̀ ajé, àtìlẹyìn àwùjọ, bí àwọn èèyàn ṣe ní àǹfàní láti lè jáde bó bá ṣe wù wọ́n sí, àti bí ẹ̀mí àwọn èèyàn ṣe le gùn sí ní orílẹ̀ èdè ogóje (140) káàkiri àgbáyé yẹ̀wò.

Fún ọdún méjì tẹ̀lé ara wọn báyìí, kò sí prílẹ̀ èdè Yúróòpù ní ipò àkọ́kọ́ sí ìkẹwàá.

Australia ló wà ní ipò kẹẹ̀dógún, Amẹ́ríkà wà ní ipò kẹtàlélógún, Canada wà ní ipò kẹẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí United Kingdom wà ní ipò kọkàndínlọ́gbọ̀n.

Ní ọdún yìí, àwọn orílẹ̀ èdè márùn-ún tó wà ní ipò àkọ́kọ́ sí ìkarùn-ún ni wọ́n ní àwọn ohun tí wọ́n fi jọra tó ń fa inú dídùn fún wọn tí a sì bá wọn sọ̀rọ̀ láti mọ nǹkan wọ̀nyí àti bí àlejò tó bá ń ṣàbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè ṣe le jẹ àǹfààní yìí.

1. Finland

Finland ló wà ní òkè téńté nínú àwọn orílẹ̀ èdè tí inú àwọn èèyàn rẹ̀ ń dùn jùlọ ní àgbáyé. Ìgbà Kẹsàn-án rèé nínú ọdún mẹ́wàá tí wọ́n wà ní ipò yìí.

Ohun tó mú orílẹ̀ èdè yìí wà ní ipò náà nib í ìwà àjẹbánu kò ṣe wọ́pọ̀ níbẹ̀ àti àtìlẹyìn tí àwọn aráàlú máa ń rí látọ̀dọ̀ ìjọba tó fi mọ́ ètò ẹ̀kọ́ àti ìlera èyí tó máa ń mú inú àwọn aráàlú dùn dáadáa.

Olli Salo sọ pé inú òun máa ń dùn pé ààbò tó péye wà ní Finland, tí ọkàn sì máa ń balẹ̀ tí àwọn bá jáde pé kò sí ohun tó máa ṣe àwọn tó wà nílé.

"Ọdún méje ni àwọn ọmọdé máa bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ níbí, tí èèyàn bá sì ṣe àdéhùn, ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n máa mú àdéhùn náà ṣẹ."

Ṣùgbọ́n àwọn aráàlú kìí rojú láti san ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó orí nítorí irú ìgbé ayé tí wọ́n ń rí.

"Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì bíi ètò ìlera, ètò ẹ̀kọ́ àti ìrìnnà ni ìjọba ń ṣe ìrànwọ́ fún, kí ló dé tí èèyàn kò ní san owó orí láti gbádùn ara rẹ̀?" Salo sọ.

Inú dídún máa ń wáyé nígbà tí èèyàn bá ń gbé ayé ìrọ̀rùn àti ìlera, Mayor Daniel Sazonov sọ. Ó ní kí èèyàn le jáde nígbà tó bá wù ú ṣe pàtàkì gidi.

2. Iceland

Iceland ti gba ipò kejì lọ́wọ́ Denmark láti fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ọdún 2024 nígbà tí wọ́n kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè àkọ́kọ́ nínú àwùjọ fáwọn èèyàn rẹ̀ jùlọ.

Bákan náà ló wà lára àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́wàá tó ń léwájú nínú pípèsè ohun èlò wọn fúnra rẹ̀ àti pípèsè ètò ìlera tó pójú owó.

Olùgbé Iceland kan, Ingibjörg Friðriksdóttir sọ pé fún ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn kò gba ìrànlọ́wọ́ láti ìta, àwọn ni wọ́n ń dá pèsè ohun gbogbo tí wọ́n nílò, èyí tó sì mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan.

Onírúurú ìjì líle ni orílẹ̀ èdè náà ti kojú.

Ní gbogbo àsìkò ni àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè náà máa ń gba àwọn àlejò ní ìmọ̀ràn láti máa jáde.

Björnsdóttir sọ pé "gbígba èémí tó dára, rírí àwọn òhún ọ̀ṣọ́ àti kí èèyàn le rìn nígbà tó bá wù ú jẹ́ ohun tó jẹ́ kí orílẹ̀ èdè wa dùn ún gbé."

3. Denmark

Denmark kò ì tíì já walẹ̀ kọjá ipò kẹrin rí láti ìgbà tí wọ́n ti ń gbé ìjábọ̀ náà síta.

Ipò kẹta ni Denmark wà lọ́dún yìí, tó sì tún wà ní ipò kẹta àwọn orílẹ̀ èdè tó ń pèsè àtìlẹyìn àwùjọ fáwọn èèyàn rẹ̀ jùlọ.

Ó wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwà àjẹbánu ti kéré jọjọ àti ipò keje nínú orílẹ̀ èdè tí ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ dára jù lábẹ́nú.

Akọ̀ròyìn Laura Halla sọ pé nígbà tí èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ nípa inú dídùn ní Denmark, kò túmọ̀ sí ẹ̀rín lẹ́nu àwọn èèyàn nìkan. "Ó túmọ̀ sí bí àwọn èèyàn ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú àwùjọ sí àti níní ìgboyà pé gbogbo èèyàn ń ṣiṣẹ́ fún àṣeyọrí.

Halla ní ọmọbìnrin méjì, tí ọkàn rẹ̀ sì máa ń balẹ̀ lórí wọn ní gbogbo ìgbà. Bákan náà ló ní òun fẹ́ràn Copenhagen èyí tó ti di ibi tí àwọn aráàlú ti le máa lúwẹ̀ẹ́ ní gbogbo ọdún.

4. Costa Rica

Costa Rica, tó wọ ipò kẹrin lọ́dún yìí ni orílẹ̀ èdè àkọ́kọ́ ní Latin America tó máa wọ ipò karùn-un.

Bí àwọn èèyàn ṣe le sọ ohun tó bá wù wọ́n àti àtìlẹyìn tí ìjọba ń ṣe ni àlékún ti bá ní ìlọ́po méjì láti ọdún 2021.

Olùgbé Costa Rica, Adrian Hunt sọ pé ohun tó mú Costa Rica dùn-ún gbé ni àwọn èèyàn tí àwọn jọ ń gbé, tí àwọn jọ ní àfojúsùn láti ní ìgbé ayé tó rọrùn.

"Mo rò pé Costa Rica ni ìgbé ayé ti rọrùn jùlọ ní Central America, nǹkankan wà nípa àwọn èèyàn, tó fi mọ́ àwọn onílé àti àlejò, èyí tó jẹ́ kí ó ṣe pàtàkì."

5. Sweden

Sweden ló wà nípò karùn-ún orílẹ̀ èdè tí inú wọn dùn jùlọ. Láti ipò kẹwàá ló ti gòkè sí ipò karùn-ún láàárín ọdún mẹ́wàá.

Ó wà ní ipò kejè nínú àwọn orílẹ̀ èdè tí ìlera wọn dára jùlọ àti ipò karùn-ún nínú àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwà àjẹbánu kò ti wọ́pọ̀.

Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìlera àti ìgbáyégbádùn àwọn èèyàn, Micael Dahlen sọ pé ìdí tí Sweden fi ń wà níwájú àwọn orílẹ̀ èdè tí inú wọn dùn lágbàáyé sọ pé orílẹ̀ èdè tó kéré ni Sweden.

"Àwọn èèyàn kò jìnà síra wọn, ìlú kò jìnà síra wọn, à ń gbé ìgbé ayé tó rọrùn, tí a sì máa ń gba àwọn èèyàn tuntun àti ìrírí tuntun láàyè.

"Kò sí irú èèyàn to jẹ́ yálà akọ̀wé, olóòtú ìjọba tàbí ọ̀jọ̀gbọ́n inú dídùn bíi tèmi, ìwọ ni ìwọ," Dahlen sọ.