Eré Àjíǹde di wàhálà! Akẹ́kọ̀ọ́ dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n lú ú bí bàrà lásìkò tó ṣe Jesu nínú eré Ajinde
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akẹ́kọ̀ọ́ ipele kejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Kampala International University, Dennis Zziwa ti dèrò ilé ìwòsàn látàrí ìfarapa tó ní níbi tí wọ́n ti ń ṣe eré láti fi ìgbé ayé Jésù hàn,
Dennis ló kópa Jésù nínú eré náà èyí tí wọ́n ṣe ní Our Lady of Africa Church ní Mbuya, orílẹ̀ èdè Uganda.
Ọ̀pọ̀ àwọn olùjọ́sìn àtàwọn òǹwòrán ló péjú pésẹ̀ sí ilé ìjọsìn náà láti wòran eré náà èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní ọdọọdún láti fi bí wọ́n ṣe kan Jésù mọ́ àgbélèbú hàn.
Ìròyìn ní ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní lu Dennis láti ṣàfihàn àwọn ìyà tí Jésù jẹ nígbà ayé rẹ̀ èyí tó mú kí wọ́n lù ú bí ẹni lu bàrà, tó sì tara bẹ́ẹ̀ farapa gidigidi.
Àwọn tó ń mójútọ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní àjọ Red Cross tí wọ́n wà níbi ètò náà ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe ìtọ́jú rẹ̀, kí wọ́n tó gbé Dennis lọ sílé ìwòsàn Lamone Health Center tó wà ní Luzira fún ìtọ́jú tó péye.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn kọminú lórí bí nǹkan ṣe yí bìrì láàárín ìṣẹ́jú péréte, bí wọ́n ṣe ní ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé eré di òótọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́ lásìkò tí wọ́n ń ṣàfihàn ohun ìgbà nnì.
Ìròyìn ní Dennis ṣì wà nílé ìwòsàn, lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, tó sì ń gba ìtọ́jú tó péye lábẹ́ ààbò tó dájú.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ń mú kí àwọn èèyàn máa kọminú lórí àwọn ètò ààbò tí wọ́n máa ń pèsè lásìkò tí àwọn eré bá ń wáyé pàápàá àwọn èyí tó jọ mọ́ ẹ̀sìn, tó sì nííṣe pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ tó gba ìfarasí àti ìjìyà lọ́wọ́.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available