Irọ́ ni pé a ti dá ẹ̀yáwó tí à ń ṣe fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dúró - NELFUND
Oríṣun àwòrán, OTHERS
Laipẹ yii ni iroyin kan gbode, pe Nigerian Education Loan Fund (NELFUND) to maa n ṣeto ẹyawo fawọn akẹkọọ ile ẹkọ giga ti da eto naa duro. Eyi ni NELFUND ti wa fesi si bayii pe irọ gbuu ni.
Loju opo X ajọ NELFUND lo ti kede lọjọ Abamẹta to kọja, pe oun ko figba kankan gbe e jade pe oun dawọ ẹyawo duro na.
Wọn ni ki araalu ma ṣe gba iroyin naa gbọ rara, afi ohun to ba ti ọdọ NELFUND wa nikan ni ki wọn maa gbagbọ bi iroyin ododo.
Kí lọ mú NELFUND ṣàlàyé?
Alaye ọrọ ti ajọ NELFUND ṣe yii n waye latari iwe kan to gba ori ayelujara kan, pe awọn ohun ti ajọ naa ko ro ṣe ṣẹlẹ, o si ju agbara wọn lọ.
Iroyin naa sọ pe fun idi eyi, wọn ti pinnu lati so ẹyawo rọ na, ati pe ẹsẹkẹsẹ lo si ti bẹrẹ.
Ko pẹ ti iroyin naa fi tan kalẹ to si di ohun to kari ẹka ayelujara.
NELFUND to si jẹ pe akọsilẹ ijọba lori rẹ sọ pe owo tijọba ti fi bo aṣiri awọn akẹkọọ labẹ rẹ ju N1.1bn lọ.
Ti wọn tun ni akẹkọọ to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọjọ (160,000) lo ti jẹ anfaani ẹkọ ori ayelujara labẹ eto ọlọkan-o-jọkan to ko sinu.
Eyi lo jẹ ki NELFUND tete kede loju opo X rẹ, pe ofege ati ayederu pọnbele ni iwe to n kede idaduro ẹyawo naa lori ayelujara.
"Ẹ jọwọ ẹ ma ṣe gba lẹta ofege to n kede idaduro ẹyawo fawọn akẹkọọ lori ayeluja gbọ. NELFUND ko gbe ohun to jọ bẹẹ jade."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade NELFUND ka.
NELFUND wa rọ awọn akẹkọọ atawọn ti ọrọ yii kan, lati maa beere ohun ti wọn ba fẹ mọ nipa rẹ loju opo awọn, lati dena iroyin ofege ti ko ri bẹẹ.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available