Wo àwọn tẹlifíṣàn àti rédíò tí àjọ NBC gbẹ́sẹ̀lé ní Nàìjíríà

Ajọ to n ṣe amojuto igbohunsafẹfẹ lorilẹede Naijiria, NBC ti wọgile iwe aṣẹ igbohunsafẹfẹ awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ mejilelaadọta kan bayii jakejdao orilẹede NAijiria.

Ohun ti ajọ NBC sọ ni pe wọn kuna lati san gbese owo iwe aṣẹ igbohunsafẹfẹ ọlọdọọdun to yẹ ki wọn san.

Oludari agba ni ajọ naa, Balarabe Ilelah ṣalaye fun awọn akọroyin nilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria pe awọn ti kọkọ fun awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ naa ni gbedeke oṣu mẹta lati san owo naa ki wọn lee fi kun ẹmi iwe aṣẹ wọn ṣugbọn wọn ko ṣe bẹẹ.

Ajọ NBC ni wọn yoo gbe awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ naa ti pa lẹyin wakati mẹrinlelogun.

NBC ni iṣẹ igbohunsafẹfẹ lai san owo iwe aṣẹ tako ofin igbohunsafẹfẹ lorilẹede Naijiria

Ni oṣu karun un, ọdun 2022 ni ajọ to n ṣe amojuto igbohunsafẹfẹ lorilẹede Naijiria, NBC gbe orukọ awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ kan jade ninu iwe iroyin pe wọn n jẹ ijọba lowo iwe aṣẹ wọn.

Oludari agba ajọ NBC, Balarabe Ilelah ṣalaye pe wọn fun awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ naa ni gbede ọsẹ meji ki wọn fi san owo naa tabi ki wọn gbẹsẹ le ikanni igbohunsafẹfẹ wọn.

O ni wọn yoo fun awọn ileeṣẹ miran to ṣetan lati tẹle ofin to de igbohunsafẹfẹ ni Naijiria ni oju opo ikanni igbohunsafẹfẹ naa.

“Lẹyin oṣu mẹta ti wọn kede orukọ naa, awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ kan lara wọn ko tii papa san owo iwe aṣẹ wọn ọhun

eleyi to tako ofin to da ajọ to n ṣe amojuto igbohunsafẹfẹ lorilẹede Naijiria, Nationa Broadcasting Commission Act CAP N11 iwe ofin Naijiria tọdun 2004 paapaajulọ abala ikẹwaa ninu ipin kẹta ofin ọhun.

“Pẹlu eyi, titẹsiwaju awọn ileeṣẹ wọnyii lati maa gbohun safẹfẹ lai sanwo tako ofin o si n tigi bo ju eto abo Naijiria.”

Orukọ awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ ti NBC gbe orukọ wọn sita pe ọrọ naa kan niyii

Adari agba ajọ NBC wa ke sawọn ẹka ajọ naa ni ipinlẹ pe ki wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajọ agbofinro gbogbo ni agbegbe wọn lati rii pe wọn fi idi aṣẹ naa mulẹ ni kiakia.

  • Silverbird   TV (Silverbird Communications  Co. Ltd) Network
  • Rhythm FM   (Silverbird Communications Ltd) FM Abuja
  • Rhythm FM   (Silverbird Communications Ltd) FM Lagos
  • Rhythm FM   (Silverbird Communications Ltd) Yenagoa
  • Rhythm FM   (Silverbird Communications Ltd) Port-Harcourt
  • Rhythm FM   (Silverbird Communications Ltd) Jos
  • Rhythm FM   (Silverbird Communication Ltd) Benin
  • AIT/Ray   Power FM (DAAR Communication ltd) Network
  • Greetings   FM (Greetings Media Ltd) Network  
  • Tao FM   (Ovidi CommunicationS Ltd) Okene
  • Zuma FM (Zuma   FM Ltd) Suleja
  • Crowther   FM (Crowther Communications Ltd) Abuja
  • We FM (Kings   Broadcasting Ltd) Benin
  • Linksman   International ltd Keffi
  • Bomay   Broadcasting Services ltd Abuja
  • MITV (Murhi   International Group Ltd)  Ibadan
  • Classic  FM (Pinkt Nigeria Ltd) Port-Harcourt
  • Classic  FM (Pinkt Nigeria Ltd) Lagos
  • Classic  TV (Pinkt Nigeria Ltd) Lagos
  • Beat FM (Megalectrics LTD) Lagos
  • Cooper Communications  ltd Lagos
  • Splash FM  (West Midlands Ltd) Ibadan
  • Rock City  FM (Boot Communications ltd) Abeokuta
  • Family FM  (Kalaks Investments Nig. Ltd) Ilugun
  • Space FM  (Creazioni Nig. Ltd) Ibadan
  • Radio  Jeremi (Radio Jeremi ltd) Effurun
  • Breeze FM  (Bays Water ltd) Akure
  • Vibes FM  (Vibes Communication ltd) Benin
  • Family   Love FM (Multimesh Broadcasting Co. Ltd) Port-Harcourt
  • Wave FM   (South Atlantic Media ltd) Port-Harcourt
  • Kogi  State Broadcasting Corporation
  • Kwara State Broadcasting Corporation
  • Niger State Broadcasting Corporation
  • Gombe State Broadcasting Corporation 
  • Lagos State Broadcasting Corporation
  • Lagos DSB
  • Osun State Broadcasting Corporation
  • Ogun State Broadcasting Corporation
  • Ondo State Broadcasting Corporation
  • Rivers State Broadcasting Corporation
  • Bayelsa State Broadcasting Corporation
  • Cross  River State Broadcasting Corporation
  • Imo State  Broadcasting Corporation
  • Anambra State Broadcasting Corporation
  • Borno State Broadcasting Corporation
  • Yobe State Broadcasting Corporation
  • Sokoto State Broadcasting Corporation
  • Zamfara State Broadcasting Corporation
  • Kebbi State Broadcasting Corporation
  • Jigawa State Broadcasting Corporation
  • Kaduna State Broadcasting Corporation
  • Katsina State Broadcasting Corporation