You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Amritsar: Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sọnù sínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú'rin lásìkò tí wọ́n n wòran ọdún
O lé ni aadọta eniyan to padanu ẹmi wọn, ti eniyan igba mi i si tun farapa lasiko ti ọkọ oju'rin kan yà wọ aarin awn ero to n woran nitosi ilú Amritsar.
Ọnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun BBC pe awọn to padanu ẹmi wọn ọhun duro ni oju ọna ọkọ oju'rin lati woran ayẹyẹ ọdun Hindu to jẹ ti Dusshera
Wọn ko si gbọ ìrò ọkọ naa nitori pe ariwo ina alarambara ti wọn tan sinu ère oriṣa Ravana ti wọn n wo lọwọ.
Awọn alaṣẹ sọ pe nkan to jẹ wọn l'ogun lọwọlọwọ ni lati gbe awọn to farapa lọ sileewosan fun itọju.
Fidio kan to wa lori ẹrọ ayelujara ṣafihan bi ọkọ oju'rin naa ṣe kọlu àwọn eniyan ọhun.
Just moments before, crowds watching the firecrackers show were asked by organisers to move back - towards the railway tracks, reports say.
Ọkọ oju'rin naa n rinrinajo lati ilu Jalandhar lọ si Amritsar.
Minisita fun ilu Punjab, Amarinder Singh ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹg bi ohun to bani lọkan jẹ pupọ.
''Ao ṣe gbogbo nkan to yẹ lati ran awn to farapa lọwọ.''
"Mo si ti paṣẹ fun awọn alakoso agbegbe naa lati ri daju pe nkankan ko mẹ́hẹ ninu itọju wọn."
Bakan naa ni olootu ijọba, Narenda Modi, sọ̀ pe iṣẹlẹ naa jẹ ibanujẹ ọkàn.
Ẹwẹ, àwọn eniyan n bẹru pe o ṣeeṣe ki awọn ti yoo ku tun pọ si.
Ijamba ọkọ oju'rin wọpọ diẹ ni orilẹede India, nibi ti awọn oju'rin ti di ti atijọ, botilẹ jẹ wi pe o ti dinku ni asiko yii.
Kini Ọdun Dusshera duro fun?
- Ayẹyẹ fun bi oriṣa Hindu, Rama ṣe bori ooṣa olori mẹrin, Ravana
- O n ṣafihan iṣẹgun ti ire ni lori ibi
- Ọdọọdun ni wọn maa n ṣe e - o si maa n waye fun oru ọjọ mẹwa gbako
- Lọdun 20015, ajọ Unesco gbe ade fun àṣà Ramlila gẹgẹ bi ''Nkan ajogun ba to gbayi laarin ọmọniyan''