Cash grant: Ìjọba àpapọ̀ bẹ̀rẹ̀ sísan N20,000 owó ìrànwọ́ fáwọn obìnrin igbèríko l'Ogun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ijọba apapọ ti bẹrẹ si ni san owo iranwọ ẹgbẹrun lọna ogun naira(N20,000) fawọn obinrin ẹgbẹrun mẹta ati abọ(3500) to wa ni igberiko nipinlẹ Ogun.

Ijọba ibilẹ ogun to wa ni ipinlẹ naa lawọn obinrin ọhun ti wa.

Minisita fun ileeṣẹ ijọba to n ri si ṣiṣe iranwọ fun araalu ati idasoke awọn eeyan, Hajiya Sadiya Faruq lo fi eto naa lọlẹ niluu Abeokuta lopin ọsẹ to lọ.

Hajiya Faruq ti akọwe agba ileeṣẹ ijọba naa, Bashir Alkali ṣoju nibi ayẹyẹ ọhun ṣalaye pe eto naa wa fun fifa awọn ti ko rọwọ họri soke.

O ni ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti n ṣeranwọ fawọn talaka lati ibẹrẹ ijọba rẹ, bo tilẹ jẹ pe idojukọ pọ fun ijọba rẹ.

Minisita ni dindin iṣẹ ku lawujọ ti di eto ti gbogbo awọn ijọba orilẹede agbaye n ṣe bayii.

''Eyi lo mu ki Aarẹ Buhari ṣe agbekalẹ eto iranwọ fawọn eeyan, National Social Investment Programme (NSIP) lati le din oṣi ku ni Naijiria,'' minisita lo sọ bẹẹ.

Hayiya Faruq ni eto NSIP ti ni ipa to dara laye awọn ọmọ Naijiria lati igba to ti bẹrẹ lọdun 2016.

Minisita sọ pe akọsilẹ fihan pe miliọnu mejila eeyan lo ti jẹ anfaani eto ọhun lati igba to ti bẹrẹ ni Naijira.

O ni bakan naa ni ijọba tun n san ẹgbẹrun marun naira fawọn eeyan bi miliọnu kan ti wọn ko rọwọ họri lawujọ.

Hajiya Faruq fikun ọrọ rẹ pe awọn olokoowo kekeke naa ti jẹ anfaani ẹyawo labẹ ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari.