Mike Sonko: Gbogbo dúkìá Gómìnà àná náà ló jẹ́ wúrà

Yoruba ni ohun to ba wu olowo, lo n fi owo rẹ se, ara to ba si wu olowo, lo le fi owo rẹ da.

Bi igbe aye ọkunrin kan Mike Sonko se ri ree, ẹni to nifẹ wura puọ, ọpọ ohun alumọni rẹ si lo jẹ kikida goolu pọnbele.

Sonko, ti inagijẹ rẹ n jẹ Sonkoree, jẹ ọdọmọde olowo lati orilẹede Kenya, bakan naa lo si tun jẹ oloselu to gbajumọ bii isana ẹlẹta.

Ẹni ọdun marundinlaadọta ni Sonko, to si jẹ gomina keji ti yoo dari ilu Nairobi amọ ile asofin agba ilk naa yọ nipo gomina lori ẹsun iwa ọdaran ati asemase.

Bi o tilẹ jẹ pe ọkunrin yii lo ni owo rẹ amọ ọpọ eeyan ni ẹnu maa n ya nipa awọn dukia to jẹ kikida goolu olowo iyebiye to maa n ra.

Wọn ni isẹ, osi ati aini gogo nilẹ Afirika ati ni orilẹede rẹ pẹlu amọ ifẹ wura lo gba ookan aya rẹ.

Awọn dukia olowo iyebiye to jẹ ti Sonko ree: