Gomina El-Rufai: Èmi àti Sanusi ti wà lọ́nà Abuja

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ati Emir tẹlẹ, Muhammadu Sanusi ti wa lọna Abuja bayii.

Ijọba ipinlẹ Kaduna lo fi lede bẹẹ loju opoTwitter wọn.

Wọn sọ wi pe awọn mejeeji ti kuro ni Awe bayii lọ si ilu Abuja.

Bakan naa ni wọn kọkọ fi lede wi pe Sanusi ti ko gbogbo ẹru rẹ kuro ni Awe ti wọn si ti n mura irinajo lẹyin ti wọn kirun tan mi Awe.

Ọpọlọpọ eniyan ati ololufẹ Sanusi lo jade lati ki pe o daabọ lẹyin ti wọn ti gbalejo rẹ lasiko ti ijọba ipinlẹ Kano yọ ọ kuro nipo gẹgẹ bi Emir ilu Kano.

Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá, DSS, ẹ fún Sanusi lómìnira àti rìn fanda padà - Iléẹjọ́ pàṣẹ

Ileẹjọ giga ijọba apapọ to kalẹ silu Abuja ti pasẹ pe ki ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS fi Emir ilu Kano ti wọn yọ nipo, Sanusi Lamido Sanusi silẹ ni ahamọ ti wọn fi si.

Adajọ Anwuli Chikere lo pasẹ kanmọ n kia naa lọjọ Ẹti lasiko to n gbọ ẹjọ ti agbẹjọro Sanusi, agba amofin Lateef Fagbemi gbe wa siwaju rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n pasẹ naa, adajọ Chikere ni "asẹ ileẹjọ yii ni pe ki ọga agba ọlọpaa, oludari ajọ ọtẹlẹmuyẹ ati agbẹjọro agba nipinlẹ Kano ati adajọ agba lorilẹede yii, ti gbogbo wọn jẹ olujẹjọ, lati ri daju pe wọn da ẹtọ ọmọniyan pada fun olupẹjọ naa gẹgẹ bo se n beere fun."

Bakan naa lo fikun pe ki wọn fi olupẹjọ ọhun silẹ kuro ni ahamọ abi igbele ti wọn fi si, ki wọn si da awọn ẹtọ rẹ bii ọmọniyan pada, eyi to nii se pẹlu ominira, ibakẹgbẹpọ ati lilọ soke-sodo rẹ yika Naijiria, yatọ silu Kano nikan ti ko gbọdọ de, titi ti wọn yoo fi gbọ ẹjọ naa tan.

Adajọ Chikere wa gba Sanusi laaye lati pin iwe asẹ ileeẹjọ naa fun ọga agba ọlọpa ati awọn olujẹjọ yoku.