You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bullion Van: Àwọn ọ̀dọ́ ìlú Akure faraya lẹ́yìn tí ọkọ̀ akówó sálọ lẹ́yìn tó pa okùnrin kan
Awọn ọdọ kan nilu Akure ti sẹwọde lodi si bi ọkọ agbówórìn "Bullion Van" ile ifowopamọ kan ṣe pa okunrin kan nilu naa.
Ọmọkunrin ọhun, torukọ rẹ n jẹ Ibikunle Abiodun, ni wọn ni ọkọ ọhun gba lagbegbe Fanibi, lopona to lọ si ilu Ondo.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe, dẹrẹba ọkọ naa ati awọn ọlọpaa to n tẹlẹ ko bikita lati duro mọ alafia okunrin ọhun, lẹyin to gba a tan, ṣugbọn n ṣe lo fẹsẹ fẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọpọ awọn eeyan ilu Akure ti bẹrẹ si ni fi eroungba wọn han lori iṣẹlẹ naa loju opo Twitter.
Awọn oluifẹhonuhan ọhun bẹrẹ iwọde wọn lagbegbe Oshinle, ti wọn si n kọ oriṣiriṣi orin aro, ki wọn to forile aafin ọba Deji ti ilu Akure.
Wọn ni wọn fẹ ki ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo foju awako naa han-de.
- Ọdọọdún làwọn ọmọ ònilẹ̀ ń dà wá láàmú ní Soka, kí Sunday Igboho tó gbà wá sílẹ̀ - Àwọn olùgbé Soka
- Inec kéde pé olùdíje gómìnà fẹ́gbẹ́ PDP ní Bayelsa làwọn gbà pé ó yege ìbò
- Arisekola ló fún mi ní ilẹ̀ tí ìjọba Ọyọ gbẹ́sẹ̀ lé, ń kò ní gbà - Ajimobi
- Ó ṣeéṣe kó má sí ẹ̀ṣọ́ aláàbò Amotekun l‘Eko - Ìjọba Eko
Ọkan lara awọn oloye pataki ilu Akure, Toyin Aladetoyinbo parọwa si awọn ọdọ naa lati ma ru ofin niroti iṣẹlẹ naa
Aladetoyinbo wa ṣeleri fun wọn pe, Kabiesi ti ilu Akure Oba Aladelusi Aladetoyinbo yoo ri pe awọn ọlọpaa ṣe iwadi to peye lori iṣẹlẹ ọhun.