You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èrò ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bi Ilé ṣe takò ìdájọ lori Omo-Agege
Ilé aṣòfin àgbà Nàìjíríà tí lọ ilé ẹjọ kòtẹmílọrùn láti yí ìdájọ Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó dá aṣòfin Omo-Agege padà sílé.
Kété ti adájọ Nnamdi Dimgba tí ilé ẹjọ gíga apapọ ni Abuja wọgi le àṣẹ lọ gbélé rẹ ti ilé aṣòfin pa fún Omo-Agege ni Ilé ti kọ iwe ẹjọ láti takò ìdájọ náà.
Bákan náà ní won fi ìkéde ìgbésè yi sójú òpó Twitter ilé aṣòfin agba.
Àríwísí ọtọọtọ ni ìkéde yìí ti mú wà lójú òpó ayelujara pàápàá jùlọ ní Facebook ati Twitter
Samuel Olakanla gba pe, bi kò ba ni ǹkan miran ninu, kò yẹ ki ilẹ ló sile ẹjọ kotẹmilọrun lori ọrọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Adesomo Ifedayo ni tirẹ gba Omo-Agege nimọran lati gbọ́ àṣẹ ile-ẹjọ pe
Àwọn kàn kúkú bu ẹnu àtẹ lù Omo Agege pé kii ṣe aṣojú dáadáa.
Kódà, ọrọ yà lọ bá ìṣúná ọdún 2018, Dino Melaye àti ọgá ọlọ́pàá tí kọ̀ láti yọjú sí ilé aṣòfin.