World Trade Centre September 11, 20 years after: Wo díẹ̀ lára bí wọ́n ṣe sàmì ìrántì ìkọlù 9/11 ní America

Wo àwọn aworan manigbagbe to jade nibi isami irannti ikọlu 9/11 lẹyin ogun ọdun to ṣẹlẹ ni America.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn to n ba ara wọn kẹdun di mọ ara wọn pẹlu omije lati ranti ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kókanla osu kesan an 2001 ti iṣẹlẹ ibanujẹ naa ṣẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Opọ ẹbi ti wọn padanu eeyan wọn nibi ikọlu ọkọ ofurufu meji to gbe awọn agbesunmọmi naa to kọlu Twin Towers ni wọn peju sibi isin iranti naa ni New York lọjọ Abamẹta

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pẹlu omije ni ọpọ bọ sita wa ṣe iranti awọn ẹni wọn pẹlu aworan wọn nibi isin iranti naa ti o bẹrẹ pẹlu agogo to dun ni asiko ti ọkọ ofurufu akọkọ kọlu North Tower

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, aago ti wọn kọkọ lu ree lasiko iranti naa ni National 9/11 Memorial Museum ni New York

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Andre Jabban ree to n ba Katie Mascall ololufe rẹ kedun nigba to duro ranti baba re Joseph Mascall to ku ni Manhattan lasiko ikọlu naa

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Diẹ lara awọn oṣiṣẹ panapana ni New York duro iseju kan fun awọn akẹgbẹẹ wọn to ba iṣẹle naa lọ

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, aarẹ bill Clinton, barrack Obama, Joe Biden ati awọn aya wọn wa nibi iranti naa ni New York 2021

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, are George Bush ati aya rẹ naa duro iṣẹju kan ni Flight 93 National Memorial to wa ni Shanksville, Pennsylvania

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ohun to ṣẹku ree ni gbongan World Trade Center leyin ikolu awon agbesunmomi naa