'Ó kìí ṣe ọmọ ìyá mi mọ́' : Wo bí ogun tó ń wáyé ní Iran ṣe ń tú ẹbí ká

'Ó kìí ṣe ọmọ ìyá mi mọ́' : Wo bí ogun tó ń wáyé ní Iran ṣe ń tú ẹbí ká

Itakurọsọ yii lo waye laarin arakunrin kan ati aburo rẹ obinrin ni ilu kan to wa nitosi Tehran, olu ilu orilẹede Iran – ti o si ṣoju awọn mọlẹbi wọn – eyi to ṣafihan bi ogun to n waye loruilẹede Iran ṣe n tu ẹbi ka ti o si n ya awọn ọmọ iya lorilẹede naa pẹlu bi orilẹede Amẹrika ati Israel ṣe n tẹsiwaju pẹlu ikọlu wọn ni Iran.

Arakunrin kan ti a mọ si Sina, ṣalaye pe nigba ti awọn ọmọ iya naa pade nile iyaiya wọn, rugudu bẹ silẹ eyi to ṣafihan ipinya laarin wọn.

Ẹgbọ̀n iya wọn to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ agbebọn Basij militia ti ijọba maa n saba n ran lati da sẹria fun awọn to ba n tako ijọba lorilẹede Iran, kọ lati ki aburo rẹ to jẹ ẹjẹ rẹ, nitori pe o n takoijọba to wa lode lorilẹede naa.