Wọ́n kó Rasheed mérò níbi ìwọ́de EndSARS lọ́dún 2020, ọdún mẹ́fà ló lò lẹ́wọ̀n
Wọ́n kó Rasheed mérò níbi ìwọ́de EndSARS lọ́dún 2020, ọdún mẹ́fà ló lò lẹ́wọ̀n
Lara awọn iwọde manigbagbe to ti waye lorilẹede Naijiria, ọkan gboogi ni iwọde EndSARS jẹ eleyii ti awọn ọdọ ti fariga nipa awọn iwa familete n tutọ tawọn ọlọpaa, paapaajulọ awọn ọlọpaa ikọ SARS n hu si araalu.
Iwọde naa to waye fun ọpọlọpọ ọsẹ loṣu kẹwaa ọdun 2020 ti pari, ṣugbọn ipa rẹ ninu aye awọn eeyan kan ko tilẹ tii pari rara.
lara awọn eeyan ti a n sọ wọnyii ni Rasheed wa.
Olugbe ilu Ibadan ni Rasheed, ilu Ibadan loun pẹlu si ti darapọ awọn oluwọde yii ko to bọ si gbaga awọn agbofinro, latibẹ lo gba de ọgba ẹwọn nibi to ti lo ọdun mẹfa aye rẹ.
Ninu ifọrọwerọ yii pẹlu BBC News Yoruba, O ṣalaye bi o ṣe di olukopa ninu iwọde naa ati bi wọn ṣe mu u.