Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lẹ́yìn tí àwọn aláṣẹ lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fìyà jẹ akẹgbẹ́ wọn lọ l'Edo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìdúnkokò àti ìfìyàjẹni tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ Igbinedion Education Centre, èyí tí fídíò rẹ̀ gba orí ayélujára lópin ọ̀sẹ̀.

Ní òpin ọ̀sẹ̀ ni fídíò kan gba orí ayélujára tó ṣàfihàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì kan tí wọ́n ń na akẹ́kọ̀ọ́ míì tó wà nílẹ̀, tó jọ akẹ́kọ̀ọ́ tó kéré sí wọn.

Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń fi bẹ́lìtì lu akẹ́kọ̀ọ́ tó wà nílẹ̀ náà nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ kejì ń tẹ àyà rẹ̀ mọ́lẹ̀, tí akẹ́kọ̀ọ́ tó wà nílẹ̀ náà sì ń pariwo pẹlu ìrora bí wọ́n ṣe ń lù ú.

Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń lu akẹ́kọ̀ọ́ tó wà nílẹ̀ náà ni ọ̀kan lára wọn tó ń ya fídíò ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń sọ fáwọn yòókù rẹ̀ pé bí wọ́n ṣe ń na akẹ́kọ̀ọ́ náà ti tó.

Ọlọpaa, ile ẹkọ bẹrẹ igbesẹ

Ninu atẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹta, agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo, Eno Ikoedem, sọ pé àwọn ti gbọ́, tí àwọn sì ti rí fídíò ìfìyàjẹni tó gba orí ayélujára náà.

Ikoedem ní Kọmíṣánnà ọlọ́pàá Edo, Monday Agbonika, ti darí ọ̀gá ọlọ́pàá agbegbe tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà láti ṣèwádìí rẹ.

"Kọmandi ọlọpaa fẹ fi da gbogbo eeyan loju pe a maa mu gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ ifiyajẹni yii, wọn yoo si foju wina ofin bo ṣe yẹ."

Bakan naa ni Ikoedem sọ pe wọn ti le awọn akẹkọọ to lọwọ ninu ifiyajẹni naa kuro nile ẹkọ yii.

Ile ẹkọ tọrọ kan paapaa ti bẹrẹ igbesẹ lori iṣẹlẹ yii bi wọn ṣe wi.

Atẹjade lati Igbinedion Education Centre, fidi ẹ mulẹ pe wọn ti le awọn akẹkọọ to wa ninu fidio to gbode naa lọ.

Ifiyajẹni to ti waye ri nile ẹkọ ni Naijiria

Eyi kọ ni igba akọkọ ti ifiyajẹni n waye laarin awọn akẹkọọ ni Naijiria, ṣugbọn eyi to gbilẹ ju ni ti ọmọkunrin kan, Sylvester Oromoni, to waye loṣu Kejila ọdun 2021, latari ohun ti awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ ṣe fun un.

Ile ẹkọ Dowen College ni Oloogbe Slyvester n lọ nigba naa. Ẹsun ti awọn obi rẹ fi kan awọn ẹgbẹ rẹ ni pe wọn fẹ mu un wọnu ẹgbẹ okunkun.

Wọ ni ọmọ awọn ko gba lo fi di pe awọn ọmọ naa bẹrẹ si I fiya ọlọkan-o-jọkan jẹ ẹ titi to fi de ibi ẹmi rẹ.

Ọrọ naa lagbara pupọ, to bẹẹ ti ọmọ Naijiria to kọwe ifisun lori rẹ le ni ẹgbẹrun lọna ọgọsan-an.

Iwe ifisun naa ni wọn fi n beere idajọ ododo fun Sylvester, akẹkọọ ọmọ ọdun mejila to n gbe lọgba ile ẹkọ, to si ti ibẹ di ero ọrun.

Iku Oromoni lo mu awọn alaṣẹ ti ile ẹkọ naa pa lai ni gbedeke igba ti wọn yoo ṣi i pada.

Eyi to si buru ni pe ọdun diẹ lẹyin iku ọmọdekunrin naa ni iya rẹ paapaa jade laye, ẹni ti wọn ni ironu iku Sylvester lo pa a.

Loṣu Kẹrin ọdun 2024 ni ijọba Naijiria ti ile ẹkọ British International School pa l'Abuja, lori awọn fọnran ifiyajẹni to jade lati ile ẹkọ naa.