Peter Okoye kéde àyípadà ọjọ́ ìbí rẹ̀ pẹ̀lú Ìbejì rẹ̀ Paul Okoye, mú ọjọ́ ìbí tuntun fúnra rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Mr P Square/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkan lara awọn ibeji akọrin PSquare tẹlẹ, Peter Okoye, ti kede wi pe oun ti ṣe ayipada ọjọ ibi oun.

Peter tawọn eeyan mọ si Mr P bayii ni wọn bi lọjọ kejidinlogun oṣu Kọkanla pẹlu ibeji rẹ Paul Okoye lọdun 1981.

Amọ, Peter ti sọ loju op ayelujara rẹ wi pe oun ko ni maa ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi oun lọjọ kejidinlogun mọ pẹlu Paul to jẹ ibeji rẹ.

Mr P sọ pe oun ti sun ọjọ ibi oun si ipari oṣu Kọkanla oṣu ibi oun bayii.

Peter sọ loju opo X rẹ pe ''mo n fi akoko yii sọ fun ẹyin ẹbi, ọrẹ, ati ẹyij ololufẹ mi pe mi o ni maa ṣe ayajọ ọjọ ibi mi lọjọ kejidinlogun oṣu Kọkanla mọ.

O fẹ ki ẹ mọ wi pe n ko ni fesi si gbogbo atẹjiṣẹ ti ẹnikẹni ba fi ranṣẹ si mi ni gbogbo ọjọ kejidinlogun oṣu Kọkanla bayii lati ki mi.

Bakan naa, n ko ni gba ẹbun ọjọ ibi kankan lójọ kejidinlogun oṣu Kọkanla mọ.

NI bayii, ọgbọnjọ oṣu Kókanla ni mo maa ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi mi bayii.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbesẹ mi niyii, ẹ ṣeun fun bi ẹ ti gbọ mi ye.''

Igbesẹ yii jẹ ọna ti aawọ to wa laarin Peter ati Paul tawọn eeyan mọ si P-Square tẹlẹ tun gba yọ.

Awọn mejeeji ti jọ gbe awọn orin bi"Personally," "Chop My Money," ati "Do Me," jade nigba ti wọn n jẹ P-Square.

Lọdun 2017 ni Peter ati Paul kọkọ ni aawọ papọ eyi to fa iyapa wọn fun ọdun marun un.

Inu ọpọ ololufẹ wọn dun nigba ti wọn pari ija lọdun 2021, amọ, ko pẹ ti onikaluku wọn tun fi lọ ni ọtọọtọ.

Lọdun 2024 ni wọn tun pinya lẹyin aawọ ti wọn ni pẹlu ẹgbọn wọn, Jude Okoye ati awọn ẹsun ti ajọ EFCC fi kan wọn.

Lati igba naa lawọn mejeeji ti n ṣe nnkan wọn ni ọtọọtọ.

Peter t gbe orin to pe akọle rẹ ni The Prodigal jade, o si sọ pe o tẹ oun lọrun bi oun ṣe da orin kọ.

Paul naa to n jẹ Rudeboy tig be orin to pe akọle rẹ ni ''Reason with Me'' jade.

Paul tiẹ sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe laipẹ yii wi pe ko si nnkan to n jẹ P-Square mọ.

Rudeboy ko tii sọ ohun kankan lori bi Peter ibeji rẹ ṣe yi ọjọ ibi rẹ pada.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post