Pásítọ̀ tó lọ gbàdúrà sí ojúbọ Osun Osogbo sọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀, Bàbá òrìṣà Osun Osogbo ní ìkọjá àyè ni
Lọṣẹ to kọja ni fidio kan bẹrẹ si n milẹ titi lori ayelujara ninu eyii ti awọn ẹlẹsin abalaye kan ti lọ bẹ ori aja sinu ilu ijọsin alasọ funfun kan.
Wọn ni awọn ṣe bẹẹ lẹyin ti pasitọ ijọ naa kọkọ lọ si ojubọ Osun Osogbo lati gbadura sibẹ to si ni oun fẹ le ẹmi Eṣu to wa nibẹ kuro.
BBC Yoruba tẹkọ leti lọ ipinlẹ Osun lati ba gbogbo awọn ti ọrọ naa kan sọrọ.
Ijọba lo ni ojubọ Osun Osogbo, ko wa fun ẹsin kan ṣoso – Pasitọ
Nigba ti pasitọ Odedoyin Ezekiel, to jẹ adari ijọ God of White Calling for all Souls Ministries niluu Ido Osun, ni ijọba ibilẹ Egbedore n ba BBC sọrọ, o ni kii ṣe aṣiṣẹ lawọn ọmọ ijọ oun fi lọ sibẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ijọba lo ni ojubọ naa, o si jẹ ibudo igbafẹ ti gbogbo araalu le yọju si.
O ṣalaye pe irinajo afẹ lawọn ba lọ sibẹ, koda ra tikẹẹti owo iwọle ki wọn to ri ibikan ti awọn kan bẹ adiyẹ si, ti wọn si ta ẹjẹ rẹ sibẹ.
O ni aworan adiyẹ ti wọn ta ẹjẹ rẹ siẹ naa loun ri ti oun fi gbadura si ojubọ ọhun gẹgẹ bii ẹni ẹmi lati re ibi yoowu ti wọn ba ṣe sibẹ kuro.
Ezekiel ni "Kii ṣe pe a lọ le Eṣu wọn jade… ibudo igbafẹ to ba ti n gbalejo, kii ṣe pe o wa fun ẹsin kan."
Ikọja aye ni wọn lọ ṣe nibẹ - Baba orisa Osun Osogbo
Ifayemi Ifabode, to jẹ baba oriṣa Osun Osogbo sọ fun BBC pe ikọja aye lawọn pasitọ naa ba lọ sidi oriṣa awọn lati lọ maa le ẹmi Eṣu ibẹ jade.
O fi kun pe ohun ti pasitọ naa atawọn ọmọ ijọ rẹ ṣe le fa ija ẹsin, ko si bojumu.
Ẹwẹ, alukoro ẹgbẹ ọmọlẹyin Krisiti lagbegbe naa, Opadotun Samson sọ pe ohun to n ṣẹlẹ laarin awọn ọmọlẹyin Kristi lasiko yii to abojuto, ko si yẹ ki wọn lọ maa tojubọ ẹsin ẹlomii.
Samson ni awọn gẹgẹ bii adari ẹgbẹ CAN ti ke si pasitọ naa ko wa sọ tẹnu rẹ lori ohun to ṣẹlẹ, amọ o kọ jalẹ lati yẹ ipe awọn si.
Wayi o, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Abiodunn Ojelabi ti rọ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ki maṣe dawọle ohun ti yoo fa ija ẹsin ki wọn si gba alaafia laaye.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ.