Kí ni ohun abàmì tó wà nínú Omi Oko ní Ilesa, tí wọn ṣe kọ́lé fún-un, yọ fèrèsé àti ìlẹ̀kùn sí?

Àkọlé fídíò, Kí ní ohun abàmì tó wà nínú Omi Oko ní Ilesa, tí wọn kọ́lé fún-un, yọ fèrèsé àti ìlẹ̀kùn sí?
Kí ni ohun abàmì tó wà nínú Omi Oko ní Ilesa, tí wọn ṣe kọ́lé fún-un, yọ fèrèsé àti ìlẹ̀kùn sí?

N jẹ ẹ ti gbọ nipa odo ti wọn kọ ile fun, ti wọn si tun yọ feresi ati ilẹkun si?

Eyi ni ibi ti eto Kayefi ọsẹ yii n gbe wa re.

Lori eto Kayefi toni, ilu Ilesa la wa nibi odo kan ti wọn n pe ni Omi Oko.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni Isokun, ni omi odo naa wa.

Omi Oko yii si jẹ ara awọn odo isẹmbaye ti ọba oke fi jinki awọn eeyan ilu Ilesa.

Ki lo de ti wọn se n pe omi naa ni omi oko?

Nigba to n salaye idi ti wọn se n pe omi yii ni omi Oko, Onisokun ti Isokun nilu Ilesa, Adebayo Ilesanmi salaye fun BBC News Yoruba pe omi sẹlẹru ni omi oko.

"Omi naa maa n ru putuputu sita, omi naa si ni orisun to pọ nibi to ti maa n tu sita.

O maa n pọnpu ara rẹ soke putuputu ni, omi naa si ni alaafia."

Ki lo mu ki omi odo oko se pataki?

Nigba ti BBC News Yoruba de ilu naa, awọn ara ilu ọhun sọ pe omi oko tutu pupọ, to ba si se n tu jade sita, yoo dabi igba ti wọn bu omi naa wa latinu ẹrọ amomitutu ni.

"Yatọ si pe omi oko maa n tutu bii yinyin, ti eeyan ba tun mu u, se ni yoo da bi ẹni pe wọn da iyọ ati suga si papọ ni.

Omi odo oko yatọ gedegede sawọn omi to ku."

Ki ni nnkan abami Kayefi to wa ninu Omi Oko ti wọn se kọle fun-un?

Ninu iwadii BBC News Yoruba, nigba ta se abẹwo si ibudo ti omi oko naa wa, ohun Kayeefi kan la ri nibẹ.

Ohun abami to n se wa ni Kayefi nibudo omi oko ni pe wọn kọ ile fun omi odo Oko lati maa gbe.

Bi wọn se n kọle fun eeyan ẹlẹran ara, ni wọn se kọ ile fun omi oko.

Koda, wọn yọ ferese ati ibi igbatẹgun fun omi oko naa.

"Wọn maa n fi omi oko ki agbo fun awọn eeyan to jẹ ọmọ olomi tutu ni"

Ninu alaye tiẹ nipa idi ti omi oko fi se pataki, Alagba Aremu Asuni, to jẹ ọkan lara awọn ọmọ idile to kọkọ tẹ agbegbe naa do, salaye pe wọn maa n fi omi oko ki agbo.

"Gbogbo awọn eeyan to jẹ olomi tutu, ti kii wẹ omi gbigbona, ni omi yii dara fun.

O ni ikoko ti wọn maa n gbe wa, lati fi omi naa ki agbo, bo se ri ni 1953 ti awa de ibi yii niyẹn.

Idi ree ti wọn se maa n ro pe omi awọn olorisa ni amọ kii se bẹẹ.

"Omi Oko ni iwulo kan to so pọ pẹlu awọn ọba to ba jẹ nilu Ilesa"

Ninu iwadii wa, BBC News Yoruba tun gbọ pe iwulo kan wa to so omi Oko yii pọ mọ awọn ọba to ba jẹ nilu Ilesa.

Alagba Aremu Asuni ni omi odo oko yii ni awọn olori Owa ma n wa pọn fun loru nigba atijọ, ti awọn Ọmọsẹ, ilari ọba yoo si tẹle wọn wa.

"Omi yii si ni Ọwa maa mu, to maa fi wẹ nigba naa amọ oju ti la lasiko yii, wọn ko se bẹẹ mọ."

Awọn eeyan agbegbe naa wa rawọ ẹbẹ sijọba lati fẹ omi odo naa loju si tori omi odo yii nikan ni awọn n mu.