Nǹkan yan nínú ìjọ Anglican, àwọn àlùfáà tó pe ara wọn ní Gafcon lábẹ́ ìjọ náà yan bísọ́ọ̀bù àgbà tuntun tako bíṣọ́ọ̀bù Canterbury

Oríṣun àwòrán, Getty Images/ bbc
Wọn ti kede ẹniọwọ Laurent lati orilẹede Rwand ni wọn ti yan gẹgẹbi olori ijọ to n polongo isin ijọ Anglican lagbaye, (Gafcon) to pinya kuro lara ijọ Anglican lagbaye ti wn kọ lati gba Biṣọọbu agba Canterbury gẹgẹbi olori wọn.
Ọkanlawọn ti itumọ rẹ lede oyinbo 'Primus Inter Pares' ni orukọ ti wọn n fun oye rẹ.
Mbanda ni olori ijọ Anglican lorilẹede Rwanda bayii, wọn si yan an nibi ipade idakọnkọ to waye nibi apejọpọ awọn alufa agba ijọ Gafcon to waye ni alẹ ọjọru.
Pẹlu eyi, ijọ Anglican to jẹ ijọ to tobiju ṣe ikẹta lagbaye tun sunmọ ipinya, pẹlu bi o ṣe ku ọsẹ mẹta ki wọn ṣeto ibura fun Sarah Mullaly gẹgẹbii Biṣọbu agba ti Canterbury.
Biṣọbu agba ti Canterbury ati ati ijọ ilẹ Gẹẹsi ko tii sọrọ kankan lori eyi.
Idibo naa jẹ ọkan lara awọn eto gboogi ti wọn la kalẹ fun ipade Gafcon ẹkẹrindinlọgbọn iru ẹ to n waye ni ilu Abuja nibi ti omilẹngbẹ awọn aṣoju lati Africa, North America ati Australia ti n kopa.
'Gafcon ko si fun iyapa ijọ Anglican, titẹle ilana Bibeli lo wa fun'

Awọn aṣoju ijọ Anglican gan wa nibi ipade naa, gẹgẹbi Ẹniọwọ Justin Muff to jẹ akọwe ipolongo fun ipade Gafcon ọdun yii.
Gafcon ni kii ṣe pe awọn fẹ yapa kuro lara ijọ Anglican rara, ati pe ọpọ awọn ọmọ ijọ Anglican lagbaye lo wa labẹ aburada rẹ. Wọn ni awọn ko fi gbogbo ara tako ki obinrin jẹ biṣọọbu agba ijọ Anglican rara, amọ wọn ni awọn ohun ti wọn pe ni 'ẹkọ ajeji' tawọn adari ijọ Anglican n mu wọle sinu ijọ ọhun lai ni idapọ kankan bi o ti wulẹ o mọ pẹlu Bibeli.
Lara awọn ẹkọ ajeji naa ni ẹkọ ṣiṣe igbeyawo akọ ati akọ pẹlu abo ati abo, to fi mọ gbigba awọn alufaa ati biṣọbu pẹlu lati ṣe bẹẹ

Oríṣun àwòrán, PA Media
Awọn alufaa kan ninu ijọ Anglican n sepade lọsẹ yii niluu Abuja ni Naijiria lati yan adari mii yatọ si adari obinrin ti ìjọ naa ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii Bíṣọ́ọ̀bù agba Canterbury ijọ naa ni Ilẹ Gẹẹsi.
Ìfilọ́lẹ̀ Arabinrin Sarah Mullally ti wọn ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bi obinrin akọkọ ti yóò jẹ Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ìjọ Anglican yoo waye loṣu yii.
Amọ, ọpọ eeyan ninu ijọ Anglican to fi de Naijiria ni ero wọn ṣọtọọtọ lori iyansipo Arabinrin Mullally.
Awọn kan gbagbọ pe ọkunrin nikan lo yẹ ko maa di iru ipo yii mu.
Awọn olùjọsìn ro dẹdẹ, wọn kan dudu ni ṣọọṣi The Vining Memorial Cathedral niluu Eko lasiko isin ọjọ isinmi to kọja.
Olùjọsìn kan, Bunmi Odukoya, faramọ iyansipo Arabinrin Mullally.
Odukoya ní "ṣiṣe iṣẹ fun Ọlọrun da lori ẹni kọọkan.
Ọlọrun le pe ọkunrin, O si tun le pe obinrin naa pẹlu.
Ẹnikẹni ti Ọlọrun ba pe ni lati jẹ ipe Ọlọrun."
Awọn eeyan mii bii Uche Nweke foju mii wo ọrọ naa nigba to sọ pe "mi o lero pe igbesẹ yii ba ọna onigbagbọ mu.
Nitori pe ko sí obìnrin ninu awọn aposteli ninu Bibeli, idi niyi ti fifi obinrin jẹ Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ìjọ Anglican ni England fi kudiẹ kaato.
Arabinrin Mullally to jẹ Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Canterbury bayii ti di adarí olùjọsìn ìjọ Anglican to to mílíọ̀nù marun un.
Lọdun 2008 ni wọn da ẹgbẹ Gafcon silẹ nigba ti ede-aiyede ṣẹlẹ lori ọrọ ifẹ akọ si akọ
Igun Gafcon ninu ijọ Anglican ko ara wọn jọ nílùú Abuja lati ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii pẹlu èròngbà láti yan adarí ijọ Anglican ti wọn.
Gafcon ni wọn ṣalaye pe awọn jẹ ojulowo ọmọ ijọ Anglican to n daabo ihinrere lágbàáyé.
Èyí wáyé lẹyin ọsẹ diẹ ti wọn yan Arabinrin Mullally sipo.
Ọjọgbọn Diarmaid MacCulloch, onímọ̀ nípa ẹsin ni fásítì Oxford ni England sọ pe"awọn olori yii ti gbogbo wọn jẹ ọkunrin lọ fun apero ni Afirika lati s'ofin lori nnkan ti ìjọ Anglican ko gba mọ."
Lọdun 2008 ni wọn da ẹgbẹ Gafcon silẹ nigba ti ede-aiyede ṣẹlẹ lori ọrọ ifẹ akọ si akọ ẹgbẹ rẹ.
Ọpọ olùjọsìn lati Afirika lo n ṣatileyin fún ẹgbẹ Gafcon.
Ẹgbẹ Gafcon ti fẹsun kan awọn adari ìjọ Anglican wí pé wọn si tun dari ìjọ naa gẹgẹ bí wọ́n ti ń ṣe e lasiko ijọba amunisin Ilẹ Gẹẹsi.
Ẹkun mejilelogoji lo wa ninu ijọ Anglican, ìjọ naa sí wa ni orilẹ-ede 165 lágbàáyé.
Anglican ni ijo to tobi jùlọ sikẹta lágbàáyé leyin ijo Katoliki ati Eastern Orthodox Church.
Bo tilẹ jẹ pe ko faramọ igbesẹ ijọ Anglican ni England, pasitọ awọn ọdọ ni Naijiria, Alexander Olasinde, sọ pe ọkan oun si maa n fa si ijọ naa.


























