Bàbá kan yìnbọn pa ọmọ rẹ̀ méje àti ọmọ ọlọ́mọ kan

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹfun aye tabi eedi ni Yoruba gba pe o le mu eeyan pa ọmọ bibi inu rẹ, amọ l'America, laaarin awon oyinbo ti ẹfun ati eedi ko si, baba kan ti pa ọmọ bibi inu rẹ meje ati ọmọ ẹnikan ti ki i se oun lo bi i.

Shamar Elkins ni wọn pe orukọ apaayan naa.

Iṣẹlẹ yii waye lọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹrin ọdun 2026, nibi to ti yinbọn laaarin eeyan ni Shreveport, Louisiana l'America.

Awọn ọlọpaa ibẹ ṣapejuwe ipaniyan naa bii "idaamu abele".

Gẹgẹ bi ẹka iroyin CBS to jẹ alabaaṣe BBC ṣe ṣalaye iṣẹlẹ naa, wọn ni awọn ọmọ to ku naa wa laaarin ọdun kan si ọdun mọkanla lọjọ ori.

Nnkan bii aago mẹwaa owurọ ni ipaniyan ọlọpọ eeyan naa ṣẹlẹ.

Ọkunrin mẹta, obinrin marun-un ni awọn ọmọ naa.

Ki lo fa ipaniyan gan-an?

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awon ẹbi tọrọ kan ṣalaye pe Elkins ati iyawo rẹ ti n ba ara wọn ja to ojo mẹta, wọn si tilẹ ti yago funra wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aburo Elkins, Troy Brown, ṣalaye fun ẹka iroyin Washington Post, pe oun gbe pelu rẹ ati pe inu ti n bi Elkins latigba ti iyawo rẹ ti ni oun ko fẹ ẹ mọ, to si n beere fun ipinya.

"Lẹyin ija akọkọ lo ti bẹrẹ si I ṣe bii ẹni pe ko mọ ohun to n ṣe mọ."

Crystal Brown, ibatan obinrin keji ti Elkins yinbọn lu, ṣalaye fun AP News Agency pe ọjọ Aje lo yẹ ki awọn tọko-taya naa foju han ni kootu lori ipinya ati ikọsilẹ wọn, ki Elkins too yinbon pa awọn ọmọ ẹ ati ọmọ ọlọmo to si tun yinbon mọ iyawo rẹ ati ibatan pẹlu.

"O pa awọn ọmọ rẹ, o yinbọn mọ iyawo rẹ. Bo ṣe pa awọn eeyan naa tan lo ji moto ti yoo maa fi sa lo, ki won too le e wọ agbegbe Cedar Grove ti won ti pada fibon pa a."

Orukọ awọn ọmọ naa bii wọn ṣe fi lede ni:

Jayla Elkins, ọmọ ọdun mẹta, Shayla Elkins, ọmọ ọdun marun-un, Kayla Pugh, ọmọ ọdun mẹfa, Layla Pugh, ọmọ ọdujn meje, Markaydon Pugh, ọmọ ọdun mẹwaa Sariahh Snow, ọmọ ọdun mọkanla, Khedarrion Snow, ọmọ ọdun mẹfa ati Braylon Snow, ọmọ ọdun marun -un.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Adari ikede ni Shreveport, Leigh Anne Evensky, ṣalaye fun BBC pe afurasi naa yinbọn mọ obinrin kan lojuu popo ko too wọ inu ile kan to wa nitosi, nibi to ti pa ọpọ mẹjọ.

"Ọkan nii awọn ọmọ naa ko tiẹ ba a tan rara."

ọlọpaa lo sọ bẹẹ.

Wọn ṣalaye pe ọkan lara awọn to yinbọn mọ naa lo wọ ile to wa nitosi si to si pe ọlọpaa.

Ko sẹni to kun afurasi apaayan naa lọwọ bi ọlọpaa ṣe wi, wọn ni funra rẹ lo da gbogbo ipaniyan naa ṣe.

"Iṣẹlẹ ibanujẹ leyi, o fẹre ma si iru rẹ ni Shreveport."

Mayor Tom Arceneaux losọ bẹẹ lọjọ Aiku naa.

O ni bi ara ṣe n kan awọn ẹbi ni ara n kan awọn ọlọpaa paapaa .

"Gbogbo ilu ilu ni eyi kan, awa naa n ba awọn ẹbi to ṣẹlẹ si kẹdun."

Bakan naa ni awọn ọlọpaa fi kun un pe awọn yoo wadii iṣẹlẹ naa dopin.

Iṣẹlẹ yii lo tun buru ju l'America, yatọ si eyi to waye loṣu Kin-in-ni ọdun 2024, nibi ti eeyan mẹjọ ti ku ni Joliet, Illinois, bii Gun Violence Archive (GVA),ṣe sọ.

Ọga ọlọpaa Shreveport, Wayne Smith, sọ pe awọn yoo siṣẹ takuntakun lati wadii ohun to ṣẹle.

Bakan naa ni Grayson Boucher, oṣiṣẹ kansu ibẹ sọ pe ìdá ọgbọn (30% ) ipaniyan to n waye ni Shreveport lo jẹ pe ifiyajẹni abẹle lo fa a, bẹẹ ni ida ọgbọn iku to n waye naa ni i ṣe pẹlu ijiya abẹle.