Ibadan Chief kidnap: Báyìí nì géńdé agbébọn ṣé na'wọ gán Olóyè Tafa àti ìyàwó rẹ́ lásìkò wẹli-wẹli òjò

Awọn agbebọn tẹnikan ko mọ ti gbe Baalẹ kan ati aya rẹ nilu Ararọmi to n bẹ ni agbegbe Bakatari nilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Ọyọ.

Iroyin sọ wi pe awọn agbebọn naa yawọ ilu Ararọmi ni Bakatari lalẹ ọjọ Iṣẹgun wọn si gbe Baalẹ, Oloye Tafa Apanpa ati aya rẹ lọ.

Bakatari ti o jẹ ọkan lara awọn ilu to n bẹ ni ijọba ibilẹ Ido wa ni opopona marosẹ Ibadan si Abẹokuta.

Bakan naa lo jẹ ilu to paala laarin ipinlẹ Ogun ati Ọyọ.

Alaye ti awọn olugbe agbegbe naa ṣe ni pe ijinigbe Baalẹ ati aya rẹ waye lalẹ l'ọjọ Iṣẹgun ninu wẹliwẹli ojo to rọ n'Ibadan.

Bakan naa ni wọn fi kun ọrọ wọn wi pe ko si ẹni to mọ ibi ti Oloye naa ati aya rẹ wa titi di asiko yii.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Adewale Osifeso fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

O ni awọn agbofinro ti bẹrẹ iṣẹ iwadi lori ọrọ naa.