You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Osun Election Results: Wọ́n ti ka ìbò Ọṣun tan, ìkéde INEC lo kù
Onikaluku n dúró de ìkéde ajọ INEC lórí idibo Ọṣun.
Awọn oludije mejidinlaadọta ni wọn figa gbaga jọ du ipo gomina nipinlẹ Ọṣun lọjọ Abamẹta, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan an, ọdun 2018.
Ibudo idibo 3,010 ni wọn fi sita fun ètò idibo naa nipinlẹ Osun pẹlu ọlọpaa 18, 426 gẹgẹ bi ọga agba ọlọpaa, Idris Ibrahim ṣe fi sita.
Bayii, ajọ eleto idibo ti ka awọn ibo ti wọn gbe wa ni eyi ti ọpọlọpọ Link ti ṣe iṣiro le lori.
Ile iṣe BBC Yorùbá naa n duro pẹlu awọn eniyan Naijiria de ikede INEC lori ijọba ibilẹ ọgbọn tidibo naa ti waye ni ipinlẹ Ọṣun.