Aretha Franklin: Gbajúgbaja olorin Amerika jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aretha Franklin nibi to ti n kọrin ni Chicago ni 1992

Gbajugbaja olorin atọkanwa (soul), Aretha Franklin, ti orile-ẹde Amerika dagbere faye.

Gbogbo aye lo n gbadura fun un lẹyin to bẹrẹ aisan ni bii ọjọ mẹta sẹyin ko to jade laye l'ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin.

Ọdun 2010 ni o kede pe oun ni aarun jẹjẹrẹ inu oronro. Agbẹnusọ rẹ, Gwendolyn Quinn, sọ pe Ọjọbọ lo ku ni ile rẹ ni Detroit, Michigan ni orilẹ-ede Amerika.

Oun ni obinrin akọkọ ti yoo wọ iwe ẹyẹ Rock and Roll. Ọdun to lọ lo tilẹ pinnu pe oun yoo fi adagba orin kikọ rọ.

Ati kekere ni arabinrin naa ti n kọrin. O bẹrẹ orin kikọ ninu ẹgbẹ akọrin ijọ New Bethel Baptist ni ilu rẹ, Detroit.

Awọn awọran igbe aye rẹ ree:

Má ṣe ri talẹnti rẹ̀ mọ́lẹ̀, Ọdọmọde olorin olokiki ni o jẹ nigba to wa l'ewe.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Onkọrin lati ọkan wa ni

Fun bi aadọrin ọdun ni obinrin naa fi kọrin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aretha Franklin kọrin fun bi aadọrin ọdun

Tẹru-tọmọ lo fẹran olorin naa ni orilẹede Amerika ati gbogbo agbaye. Ibi to ti n kọrin ni White House re ni ọdun 2016 nigba ti Barack Obama jẹ aarẹ.

Oríṣun àwòrán, NICHOLAS KAMM

Àkọlé àwòrán, Iṣẹ ori ran mi ni mo n ṣe

Oun ni olorin gboogi to kọrin nigba ti wwọn bura fun Barack Obama gẹgẹ bii aarẹ orilẹ-ede Amerika.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O kọrin niwaju gbogbo alagbara Amerika nigba ti Obama di aarẹ.

Oun ati Donald Trump ree ni ọdun 1987 nigba ti ko ṣi ẹnikankan to ro pe o le di aarẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ronke Oṣodi: òótọ́ ọ̀rọ̀ máa ń korò gan ni f'áwa èèyàn