Wo bí wọ́n ṣe ṣe ọjọ́ ìbí Anabi ní Abuja ati ní Ghana

Oriṣiiriṣii ètò ni wọn ṣe láti sàmì ayẹyẹ ọjọ ìbí Anabi Muhammed (SAW) ni Abuja tó jẹ́ olu ilu Naijiria àti ni Ghana.

Àkọlé àwòrán, Eid-el-Maulud ni ọdun ayajọ ọjọ ìbí Anobi Muhammed ti ọpọ musulumi fi n ranti igba ti a bi ojiṣẹ nla
Àkọlé àwòrán, Ojo kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 2019 ni wọn sami ayẹyẹ yii ni Naijiria lọdun yii nibi ti ọpọ ti fi idunnu wọn han
Àkọlé àwòrán, Opọ awọn olufọkansin ni wọn jade wa sami ayẹyé ọjọ ibi Anobi kaakiri Abuja
Àkọlé àwòrán, Ọdọmọkunrin yii ni lati sun , ko sinmi diẹ lẹyin to ti rin fun ọpọlọpọ wakati to fi n ṣajọyọ ọjọ nla oni
Àkọlé àwòrán, Awọn miran n ke keu bi wọn ṣe n kopa ninu irin naa ni Abuja.

Oríṣun àwòrán, @ancestry

Àkọlé àwòrán, Awọn agbagba ninu ẹsin Islam ni Ghana lasiko ti wọn n sami ayẹyẹ ọjọ ibi Anọbi
Àkọlé àwòrán, Awọn aafa nlanla ni Ghana lasiko ayeye naa ni Ghana
Àkọlé àwòrán, Waasi lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi Anobi todun 2019 ni Ghana
Àkọlé àwòrán, Awon aafa nla n fi ayọ wọn han ni Ghana
Àkọlé àwòrán, Awọn ijọ ẹlẹsin loriṣiiriṣii jọ rin lopopona Abuja lati sami ọdun oni
Àkọlé àwòrán, Awọn ọdọ ṣe idije kike kurani lati fi sami ayẹyẹ naa ni Abuja
Àkọlé àwòrán, Tọkunrin tobinrin lo jade lati fi ayọ wọn han loni fun ayeye ọjọ ibi Anobi ni Abuja

Oríṣun àwòrán, Ancestry

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan n to lọwọọwọ ni Ghana lati sami ayẹyẹ ọjọ ibi naa
Àkọlé àwòrán, Ọpọ awọn ọdọ ninu ọkọ akero ati ọkada alupupu ti wọn n fayọ wọn han lori ayajọ ọjọ ibi Anọbi