Calabar Carnival 2018 kún fún oríṣiríṣi àṣà àti ìṣe

Oṣù Kejìlá ọdọọdún ni ayẹyẹ Calabar Carnival ma n wáyé ní ìpínlẹ̀ Cross Rivers fún ìgbélárugẹ́ àṣà.

Àkọlé àwòrán, Olúkòso arẹ̀kújayé pidán lójú gbogbo ènìyàn
Àkọlé àwòrán, Ọmọ Yorùbá ń tàdí réke gẹ́gẹ́ bí onílù ṣe ń kán'lù sí i níbàdí
Àkọlé àwòrán, Àwọ̀ àsìá orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni àwọn kan tilẹ̀ fi ṣe ara wọn l'ọ́ṣọ̀ ọ́
Àkọlé àwòrán, Àtèèyàn àteégún ló pitú ijó
Àkọlé àwòrán, Àwọn ọmọge awẹ́lẹ́wà gan an kò gbẹ́yìn pẹ̀lú àwọn nkan tí wọ́n fi ṣara l'óge
Àkọlé àwòrán, Níṣe ni ìlù Bàtá n ró pọnlá-pọnlá látọwọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ káàrọ̀ ò jíire
Àkọlé àwòrán, Àwọn ti ẹ̀yà Igbo nàá wá s'ágbo àríyá
Àkọlé àwòrán, Gbogbo nkan tó wáyé ní Calabar Carnival 2018 fihàn pé Nàìjíríà kún fún àwọn àṣà tó gbayì
Àkọlé àwòrán, Àṣà tí a kò bá fihan ọmọ, yóò parun. Àwọn ọ̀dọ́langba nàá kò gbẹ́yìn níbi ayẹyẹ nàá
Àkọlé àwòrán, Ijó Yorùbá gbayì púpọ̀ níbikíbi ó sì máa ń wu ni lórí jọjọ
Àkọlé àwòrán, Aṣọ àti àwọn ìlẹ̀kẹ̀ tó j'ojú ní gbèsè n pe ara wọn rán níṣẹ́ ní Calabar Carnival 2018
Àkọlé àwòrán, Àjó làágùn l'áwọn olùkópa jó níbi ayẹyẹ Calabar Carnival 2018
Àkọlé àwòrán, Ó jọ bíi kóle kóle ṣùgbọ́n ìgbádùn láwọn ijó bá dé ni Calabar Carnival 2018