Timini ṣàlàyé fún BBC lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàrin òun àti Funke Akindele
Tobi Makinde ti ọpọ eeyan mọ si Timini lo saba maa n fi oju han ninu awọn sinima ti gbajumọ osere tiata lede Yoruba ati oyinbo, Funke Akindele ba se.
Amọ Timini kii saba ba awọn osere tiata miran kopa ninu sinima wọn.
Timini se igbeyawo laipẹ yii, ti Funke Akindele ko si yọju sibẹ.
Idi ree ti awuyewuye se gba ori ayelujara pe aawọ wa laarin Funke Akindele ati Timini, ni Funke se fidi mọle lasiko igbeyawo osere tiata naa.
BBC News Yoruba wa Timini kan lati mọ boya lootọ ni aawọ wa laarin ohun ati Funke Akindele.
" A ko le kọ itan igbe aye Tobi Makinde lai kọ nipa awọn obi mi, Tunji Bamisigbin, ẹni to fun mi lanfaani lati wọ agbo ere tiata ati Funke Akindele to sọ mi di gbajumọ osere"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Timini sọ nipa ibẹrẹ aye rẹ, to si ni a ko le kọ itan igbe aye oun lai ma sọ nipa ipa ti isọri awọn eeyan mẹta ko nibẹ.
Isọri awọn eeyan naa ni awọn obi rẹ, ẹni to kọ nisẹ tiata, Bamishigbin ati Funke Akindele to sọ di gbajumọ osere.
Tobi Makinde ni gbajumọ osere tiata ni baba oun, oun si lo fi isẹ ere sise le oun lọwọ.
"Awọn obi mi gan lo fi isẹ tiata le mi lọwọ nitori pe baba mi jẹ osere, idi si niyi ti mo fi bẹrẹ isẹ tiata lati kekere.
Ti ẹ ba n kọ itan aye Tobi Makinde, ẹ maa kọ nipa orukọ awọn obi mi, Tunji Bamisigbin, ẹni to kọkọ fun mi lanfaani lati wọ agbo tiata, to ni igbagbọ ninu mi ati Funke Akindele."
"Baba mi lo fọna isẹ tiata han mi, mo kopa ninu ere sinima akọkọ lọdun 1998 nigba ti mo wa ni ọmọ ọdun meje"
Timini tun salaye siwaju pe nigba ti oun kere, oun maa n ri baba oun lori tẹlifisan ti o n kopa ninu ere tiata.
O ni oun si maa n sọ fun pe oun ri ninu ere amọ nigba to di ọjọ kan ni baba oun gbe oun sinu mọto lọ sibi kan.
"Nigba ti a de ibẹ, ki n to wo ọtun ati osi, mo ti ba ara mi ni awujọ awọn osere tiata ti wọn ti n se sinima.
Awọn ti mo maa n wo lori tẹlifisan, ni mo ri loju aye.
Inu mi dun, igba yẹn ni mo bẹrẹ ere tiata, alagba Tunji Bamisigbin si lo dari ere naa lọdun 1998, ọmọ ọdun meje ni mi nigba yẹn."
Ki lo fa ija laarin Timini ati Funke Akindele?
Nigba to n dahun ibeere yii, Timini ni loju opo ayelujara lawọn eeyan ti maa n kọm itan to ba wu wọn, ti wọn yoo si wa osere tiata to ba wu wọn si aarin itan ti wọn kọ.
"Ko si ohunkohun to sẹlẹ laarin emi ati Madam Funke, asiko ti mo n se igbeyawo, naa ni wọn n se agbelarugẹ sinima wọn.
Gbogbo eeyan lo si mọ pe ti wọn ba ti n se ikede sinima wọn, nnkan ti wọn maa kọju mọ niyẹn.
Nnkan yii ye mi daada pe wọn ko wa sibi igbeyawo mi, awọn eeyan pọ ti mo pe, amọ ti wọn ko wa, awọn ti wọn jẹ ọrẹ mi pẹlu.
Amọ tawọn ara ayelujara ba ti nnkan, wọn yoo kan maa sọ ero tiwọn ni."
Tobi Makinde tẹsiwaju pe o ni awọn idagbasoke kan ti eeyan maa n ni nile aye, ti yoo mu ayipada ba ọpọ nnkan.
O fikun pe awọn eeyan kan wa ti eeyan maa n ri tẹlẹ, ti ko si ni ri mọ, amọ kii se fun aidaa, fun idagbasoke ni sugbọn eyi kii ye ọpọ eeyan.
"Afojusun mi ni lati buyọ kọja ibi ti mo wa"
Nigba to n sọrọ lori afojusun rẹ, Tobi Makinde ni ọna lati tayọ kọja ipo ti oun wa bayii ni afojusun oun.
"Mo fẹ buyọ kọja Naijiria lọ si Afirika, lọ si gbogbo agbaye, adura ti mo n gba niyẹn.
Ibi ti mo wa yii ni mo n gbadura fun tẹlẹ, pe ki emi naa le maa gbe sinima sita, mo dẹ ti se eyi, ko si nnkan to ni ka ma dagba ju ibi ti a wa yii lọ."
Tobi Makinde wa seleri pe ibi ti ọkan oun wa ni lati gbe sinima sita ti yoo jẹ itẹwọgba ni gbogbo agbaye."