Ọmọ ìyá kan náà méjì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá iná l'Ondo, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana kan n pana to n jo ile

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹbi Ọgbẹni Peter Ohwo ti wa ninu ibanujẹ bayii lẹyin ti ọmọ wọn meji, Queen Ohwo ati Everlyne Ohwo jona raurau nibi ijamba ina to ṣẹlẹ nile wọn to wa lopopona 1, Olaribigbe Street, Zion Area, Ode-Aye, ni ijọba ibilẹ Okitipupa ni ipinlẹ Ondo.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ wi pe aibikita obi awọn ọmọ naa lasiko ti wọn n dana lọwọ lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, DSP Jimoh Abayomi, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe Kọmisọna ọlọpaa Adebowale Lawal ti paṣẹ iwadii ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ijamba ina ọhun gan an.

Queen Ohwo to jẹ ẹgbọn ninu awọn meji to jona mọle ọhun lo jẹ ọmọ ọdun mẹfa nigba ti aburo rẹ Everlyne jẹ ọmọ ọdun mẹrin.

Awọn ọlọpaa ti ṣabẹwo sibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, wọn si ya fọto awọn nnkan ti wọn ri nibẹ fun iṣẹ iwadii ti wọn n ṣe.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe oku awọn ọmọ to jona naa lọ si ileeṣẹ eto ilera to wa ni Ode-Aye.

Iṣẹlẹ naa si n ṣe awọn obi awọn ọmọ to padunu ẹmi wọn ni kayeefi.

Awọn ọlọpaa ko jẹ ki ẹnikẹni debi ile to jona naa mọ, bi wọn ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ panapana lati ṣewadii ohun to ṣokunfa ijamba ina ọhun.

Nigba to n kẹdun pẹlu idile to padanu ọmọ meji naa ninu ijamba ina, kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ondo, CP Adebowale Lawal, rọ awọn araalu lati ṣọra ṣe pẹlu awọn nnkan ti wọn n lo lati fi dana.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni eleyii ṣe pataki lati dẹkun iru iṣẹlẹ ina bayii lọjọ iwaju.

''Ẹ gbe awọn nnkan to le gbina kuro nibi ti ẹ ti n dana''

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti wa rọ araalu lati mojuto nnkan ti wọn ba n se lori ina, ki wọn si ma ṣe kuro nibẹ lọ sibomiran papaa julọ tawọn ọmọde ba wa nile.

''Ẹ gbe awọn nnkan to le gbina kuro nibi ti ẹ ti n dana.

Ẹ ri i wi pe ẹ ko fi awọn ọmọde nikan sinu ile nigba ti ẹ ba n dana lọwọ.

Bakan naa, ẹ gbiyanju lati ni awọn nnkan ti ẹ le fi pana ninu ile bii omi ọsẹ, yẹpẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ẹ gbiyanju lati ṣe ilanilọye fun ẹbi yin papaa julọ awọn ọmọde lori ewu to rọ mọ ina ati ohun ti eeyan le ṣe ti ina ba ṣẹyọ,'' Kọmiṣọna ọlọpaa lo sọ bẹẹ.

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Ondo wa fi da awọn araalu loju wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kaarẹ nipa didaabo bo wọn ati dukia wọn.