Anthony Obiagbaoso Enukeme: Àkójọpọ̀ àwòrán àràǹbarà nípa ìsìnkú ọlọ́rọ̀ ọmọ Nàíjíríà

Anthony Obiagbaoso Enukeme ni alaṣẹ agba fun ileesẹ elepo rọbi Tonimas oil, ọmọ bibi ipinlẹ Anambra nii se.

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Ijọ aguda James mimọ to wa ni Neni ni wọn ti se isin ikẹyin fun oloogbe Anthony Obiagbaoso Enukeme, awọn Bisọọbu agba meji si lo lewaju isin ikẹyin naa.

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Opin ọsẹ yii ni wọn sin Anthony Obiagbaoso Enukeme nilu rẹ, Neni tilu tifọn pẹlu posi olowo iyebiye ti wọn lo to miliọnu mẹrinlelọgbọn naira

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Ọjọ kẹsan osu Kẹfa ọdun 2020 ni Anthony Obiagbaoso Enukeme jade laye, ti wọn si sin lọjọ Ẹt, ọjọ Kẹrinla osu kẹjọ ọdun 2020 tilu tifọn

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Anthony Obiagbaoso Enukeme ni wọn se ayẹyẹ isisnku ọlọjọ meji fun, eyi to dun, to si larinrin

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Anthony Obiagbaoso Enukeme jade laye lẹni ọdun mẹrindinlọgọrin lawọn ara ilu rẹ fẹran rẹ tori o maa n ko awọn olokoowo wa dale isẹ silẹ milu abinibi rẹ.

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Anthony Obiagbaoso Enukeme wọlẹ lọ pẹlu oriyin nla lati ọdọ awọn eeyan ilu rẹ, atawọn oloselu

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Lara awọn eeyan jankan jankan to peju sibi isinku Anthony Obiagbaoso Enukeme ni gomina ipinlẹ Anambra, Willie Obiano

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Posi awodamiẹ́nu naa ree, to n wọ ẹsẹ mẹfa lọ, eyi ti yoo gbe Anthony Obiagbaoso Enukeme re ile ayeraye

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Iroyin kan ni miliọnu mẹrinlelọgbọn naira ni wọn fi ra posi ti wn sin Anthony Obiagbaoso Enukeme si

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Iyawo ati awọn ọmọ lo n selede tẹyinse fun Anthony Obiagbaoso Enukeme

Oríṣun àwòrán, ABS

Àkọlé àwòrán, Awọn agba bisọọbu ijọ aguda meji lo lewaju isinku fun Anthony Obiagbaoso Enukeme