Biafra at 50: Àwòrán mánigbàgbé nípa ogun abẹ́lé Nàíjíríà

Ọjọbọ, Ọjọ Kẹẹdogun, osu Kinni, ọdun 2020 lo pe aadọta ọdun ti ogun abẹle ni Naijiria wa sopin eyi ta n se iranti rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aye n lọ, a n tọọ. Ẹ́ wo ohun ija ti wọn fi ja ogun abẹle ni aadọta ọdun sẹyin. Arugbo soge ri ni

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi ilẹ yii ko ba se e gbe, a lọ gbe ilẹ miran lawọn eeyan ti ogun abẹle ka mọle n sọ nilẹ Ibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O ma se o. Ile yii ni wọn kọ lasiko ogun abẹle Biafra, to si wo lasiko ogun abẹle naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Haba! Ki lo le to eyi, Eeyan kan ibọn mẹrin. Orukọ wo la ba fun akọni ologun yii
Àkọlé àwòrán, Haa, Ẹ wo awọn akọni ologun to ja ogun abẹle ni aadọta ọdun sẹyin. Ọpọ wọn yoo ti di baba agba lasiko yii

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ki wa ni obinrin yii lee se to fi n jẹ iru iya bayii? Apa ọwọ rẹ yii, se o lee jinna bi? Nitori ogun Biafra a lọ tabi a ko lọ yii naa ni

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọlọrun ma jẹ ki abiyamọ fi oju sunkun ọmọ, ọmọde kan ree to ba ogun abẹle lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ohun to n pa oloko lẹkun, ni aparo awọn eeyan kan fi n se ẹrin rin. Nibi ti ogun ti n waye lawọn agbegbe kan, lawọn kan n fi ọti se faaji nibomiran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ado oloro lo wo ile mọ iya yii lori lasiko ogun abẹle, haa, oju ma ri to o

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oluwa oo, aduru ibọn yii ni wọn fi ja ogun abẹle! Se ilu ko ti run bayii?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ awọn ologun to jẹ alaabọ ara ilu to wa nigboro, ni wọn ti fi ẹmi wọn lelẹ fun isọkan Naijiria nigbakan ri bii ti ọkunrin yii

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ija pari, ọtẹ buse, a dupẹ ogun pari. Orin yii ni awọn ologun yii mu bọnu lẹyin ti wọn kede pe ogun abẹle ti wa sopin lọdun 1970