Revolution Protest: Wámú-wámú ni àwọn òsìsẹ́ aláàbò dúró nibí tí ìwọ́de Revolution Now ti fẹ́ wáyé

Àwọn ọlọ́pàá sọ pé ìwọ́de Revolution Now jẹ́ ìdìtẹ́ mọ́ ìjọba orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Àkọlé àwòrán, Títì pa ni pápá ìṣeré gbogboogbò ní Surulere nílùú Eko wà ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé
Àkọlé àwòrán, Àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò kò jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ ẹ̀ ṣe eré ìdárayá ní pápá ìṣeré gbogboogbò ní surulere rááyè wọlé.
Àkọlé àwòrán, Tìbọn-tìbọn ni àwọn ọmọ ogun dúró.
Àkọlé àwòrán, Àwọn tí kò ráàyè wọlé sí pápá ìṣeré bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu bí àwọn òṣìsẹ́ aláàbò kò ṣe jẹ́ kí wọ́n o wọlé
Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ileeṣẹ ologun naa kò gbẹ́yìn níbẹ̀.
Àkọlé àwòrán, Ẹnu ọ̀nà yìí ló yẹ́ kí ìwọ́se Revolution Now ó ti bẹ̀rẹ̀ l'ékòó, ṣùgbọ́n kò sí olùwọ́de kankan ni ààrọ̀ kùtù
Àkọlé àwòrán, Kìíṣe ẹnu ọ̀nà pápá ìṣeré nìkan ni àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò dúró sí.
Àkọlé àwòrán, Ó nú rúgbó bọ̀! Ọlọ́pàá àti àwọn ìkọ̀ #RevolutionNow ń tahùn sí ara wọn.