Àràmọ̀ǹdà àwòràn láti ilẹ̀ àdúláwọ̀ lọ́sẹ̀ yìí

Akojọpọ awọn arimaleelọ awopadasẹyin aworan lati ilẹ adulawọ fun ọsẹ yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn onílù tó ń kan ìlù síbàdí àwọn èèyàn níbi àyẹyẹ ìbúra gómìnà tuntun ní Eko, lórílẹ̀ Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn asoju ẹgbẹ oselu alatako MDC n dibo lati yan aarẹ tuntun lọjọ Aiku nilu Gweru lorilẹede Zimbabwe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Toru-toru lawọ̀n alatilẹyin ẹgbẹ oselu MDC fi duro ti ibo wọn, ti wọn si n reti esi ibo ọhun titi wọ idaji ọjọ keji, tii se ọjọ Aje

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi esinsin ba ta firi, maa wọn, ni ọ́logun yii n wi lasiko eto ibura fun aarẹ Mutharika ni ilu Blantire, lorilẹede Malawi

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ko si ohun tẹ le e fi mi se ni ọkunrin yii n wi, lasiko to ro asia orilẹede Algeria pẹlu ododo pupa lọwọ, to si doju kọ awọn agbofinro lati se iwọde pe ki ijọba orilẹede naa yẹba lori aleefa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oju oro lo n leke omi, osibata ni i leke odo. Sugbọn ọpọ oju oro ati osibata to n gba oju awọn odo to wa nilu Eko kan, to fi mọ awọn odo to wa lawọn agbegbe eti okun ti di irawọ ọsan to n ba awọn agba lẹru bayii, to si n di awọn apẹja ati igboke-gbodo ọkọ lọwọ lorilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, N jẹ ẹmọ pe odo nla lo wa ni abẹ afara yii tẹlẹ, ti wọn n pe ni odo Merille, lorilẹede Kenya, sugbọn ẹẹrun lo mu ki odo naa gbẹ, ti ọkunrin kan si n mu Rakunmi rẹ rin kọja lori odo to ti gbẹ naa.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ooru amuju, to ti wọ Sẹlisiọ̀si marundinlaadọta, lo mu ki ọkunrin ara Egypty yii ati ẹsin rẹ bẹ sinu odo nla kan, lati gba itura ni ilu Cairo lọjọ Ẹti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ibọn n dun lakọ lakọ lorilẹede Libya, nigba ti awọn ọmọ ogun to n satilẹyin fun ijọba ti gbogbo agbaye gbaruku ti, n waako pẹlu awọn ọmọ ogun to n se atilẹyin fun Khalifa Haftar ni ilu Tripoli l‘Ọjọbọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi o tilẹ jẹ pe ogun n l lọwọ lawọn agbegbe kan lorilẹ ede Libya, amọ eni agbegbe miran nilu Tripoli, ogun naa ko di awọn ọdọkunrin yii lọwọ lati se idije bọọlu alapẹrẹ lọjọ Aje

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn baalu yii lo n fo kaakiri ori papa Loftus Versfeld lasiko ti wọn n se ibura fun aarẹ Cyril Ramaphosa ti orilẹede South Africa lọjọ Abamẹta

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gbogbo ireti awọn ọmọ ẹgbẹ to jẹ isẹda kannaa, ti wọn n fẹ ara wọn lorilẹede Kenya lo ja si pabo, nigbati ile ẹjọ to ga julọ faake kọri lati wọgile awọn ofin to de ki akọ ati akọ tabi abo ati abo maa fẹ ara wọn lọjọ Ẹti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Obinrin kan ree lọjọ Satide nilu Dakar, lorilẹede Senegal, to ni ki wọn fi ọda se aworan egbo si oun lori, lati tako hihu iwa ipa sawọn obinrin lorilẹede naa.