NigeriaDecides2019: Kátàkátà ti bẹ̀rẹ̀ láwọ̀n agbègbè míì, tí ìlú míì sì dá

Aarọ ọjọ idibo aarẹ gan ni ajọ eleto idibo Naijiria kede pe eto idibo naa ko ni lee waye mọ.

Àkọlé àwòrán, Àwọn agbófinró rèé nó Ondo, tí wọn dí ojú ọ̀nà áíbaàmọ̀....
Àkọlé àwòrán, Awọn agbofinro ree, ti wọn duro gbagba gbaa sile iṣẹ ajọ eleto idibo
Àkọlé àwòrán, Awọn ọlọpa tun ree ti wọn di oju ọna ladugbo miran, laimọ pe......
Àkọlé àwòrán, Abẹ atibaba yii ni awọn oludibo n gbero lati fori pamọ si lasiko idibo nitori oorun, amọ riro ni ti eniyan, ṣiṣe ni ti Ọlọrun
Àkọlé àwòrán, Inu gbọngan yii ni ajọ eleto idibo ti seto rẹ silẹ pe wọn yoo ti kede apapọ esi ibo nipinlẹ Ondo, amọ bi wọn ti n fẹ, kọ lo ri
Àkọlé àwòrán, Idaji kutukutu lawọn eeyan ipinlẹ Ondo ti bọ sita lati wa se ojuse wọn, amọ o seni laaanu pe ajọ Inec ja wọn ni tanmọ
Àkọlé àwòrán, Ajimuna lawọn eeyan fi eto idibo aarẹ se ni Ondo, sugbọn o ye Ọlọrun
Àkọlé àwòrán, Ero ree nita, ti wọn fẹ dibo. O ma se o.
Àkọlé àwòrán, Paroparo ni ileepo da ni Ondo
Àkọlé àwòrán, Araalu ati Sọja n wo ara wọn. Ki lo de o?
Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan ilu Ibadan ko tilẹ fi akoko sofo, kia ni awọn kẹkẹ Maruwa ti jade lati sisẹ nigba ti ibo ko waye mọ