Nigeria Elections 2019: Bí àjọ INEC tí ṣé n palẹmọ dé ìdìbò ọjọ ẹtì

Ilé ìṣẹ́ ìròyìn BBC ti balẹ̀ bage láti má mú gbogbo ìròyìn nípa ìdìbò Nàìjíríà wà fún yín lẹsẹsẹ

Àkọlé àwòrán, Ni ileeṣẹ INEC to wa ni Yaba nipinlẹ Eko, awọn ọlọpaa n bẹ́ nilẹ lati ri wi pe ohun gbogbo lọ nmi irọwọrọsẹ.
Àkọlé àwòrán, Awọn ohun elo idibo ti de si ilu Eko lọjọọru saaju idibo ti yoo waye lọjọ ẹti
Àkọlé àwòrán, Nileeṣẹ Inec nilu Yenegoa,ipinlẹ́ Bayelsa, awọn nnkan elo idibo yi n duro de ki wọn ṣe aato wọn.
Àkọlé àwòrán, Awọn amoju ẹrọ Inec yi nilu Eko naa ko gbẹyin nibi ti wọn ti n ṣe eto ero idibo ti a mọ si 'card reader'
Àkọlé àwòrán, Ẹ ro wi pe ẹbun ayajọ olulufẹ ni wọn ko kalẹ yi?Rara awọn ẹrọ ti wọn fi n yẹ kaadi idibo wo ti wọn ko ti yọ ninu pali niwọnyi.
Àkọlé àwòrán, Ko gbọdọ din.Arakunrin yi n ka awọn nkan elo idibo ti wọn gbe wa si ileeṣẹ Inec nipinlẹ Eko
Àkọlé àwòrán, Bi awọn ero ti wọn fi n yẹ kaadi idibo ti ṣe ri niyi saaju ki wọn to ṣakojọpọ wọn
Àkọlé àwòrán, Iṣe gbomi.Amoju ẹrọ Inec yi fagidi siju soke nibi ti o ti n ṣiṣẹ lori ẹrọ kaadi idibo.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Lọjọ iṣẹgun nilu Awka nipinlẹ Anambra State ni ina jo awọn ẹrọ kaadi idibo to to ẹgbẹrun mẹrin amọ ajọ Inec ni mimi kan o mi awọn pẹlu ipalẹmọ de idibo naa.

Oríṣun àwòrán, NAF

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ileeṣẹ ologun ofurufu Naijiria naa ṣe iwọn ti wọn le ṣe nigba ti wọn fi ọkọ baalu gbe awọn nnkan elo idibo lọ si ibi ti wọn yoo ti lo wọn jakejado Naijiria.