Ìbúra Gómìnà: Tinubu, Oluwo àtàwọn èèkànlú míì ló péjú síbi ìbúra Oyetọla

Se ni aṣọ n pe aṣọ ransẹ nibi ayẹyẹ ibura fun gomina tuntun nipinlẹ Ọsun, Alhaji Gboyega Oyetọla lọjọ Isẹgun.

Oríṣun àwòrán, @Oyetola_Gboyega

Àkọlé àwòrán, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu atawọn obinrin miran toju wọn gun rege ko gbẹyin nibi ayẹyẹ ibura naa

Oríṣun àwòrán, @Oyetọla_Gboyega

Àkọlé àwòrán, Ayẹyẹ ti awọn obinrin arẹwa ko ba peju si, ode naa ko lee dun. Awọn amodedun ree nikalẹ

Oríṣun àwòrán, @Oyetọla_Gboyega

Àkọlé àwòrán, Ẹsẹ ko gbero pẹlu ọpọ alejo nilu Osogbo

Oríṣun àwòrán, Omominjo Sunday

Àkọlé àwòrán, Ayẹyẹ ibura ku ọla ni Oloye Bọla Tinubu de silu Osogbo fun ayẹyẹ ibura naa
Àkọlé àwòrán, Se ni asọ ẹgbẹjọda n pe asọ ẹgbẹjọda ransẹ nilu Osogbo
Àkọlé àwòrán, Awọn Oriade ati ọrun ilẹkẹ joko wa wa wa sibi ayẹyẹ ibura naa, ninu wọn la ti ri Oluwo tilu Iwo
Àkọlé àwòrán, Awọn oloye atawọn ọtọkulu ilu n duro ki ayẹyẹ naa bẹrẹ
Àkọlé àwòrán, Gbagede ibura kun fun ọpọ ero nilu Osogbo
Àkọlé àwòrán, Oluwo ati Ọba kan fi ijoko wọn yẹ gomina tuntun si
Àkọlé àwòrán, Awọn obitibiti ọdọ ko see ka nibi ayẹyẹ ibura naa

Oríṣun àwòrán, Omominjo Sunday

Àkọlé àwòrán, Lara awọn alejo to kọkọ de silu Osogbo nigba ti ọjọ ayẹyẹ ku ọla, ni asaaju ẹgbẹ oselu APC ni Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu.
Àkọlé àwòrán, Asaaju ogun ti kii kẹyin ogun ree nibi ayẹyẹ ree