Ìkọlù Yobe: Wo dúkìá àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìrin Dapchi

Àwọn ákọroyín BBC ya àwòrán dúkìá àádọ́fà akẹ́kọ̀ọ́bìrin tí wọ́n jí gbé ní Dapchi.

Àkọlé àwòrán, Ìjọba Nàìjííà ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àwọn àádọ́fà akẹ́kọ̀ọ́bìrin ni ágbébọn Boko Haram jí lọ
Àkọlé àwòrán, Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìrin náà fi ilé-ìwé wọn sílẹ̀ láì dágbérẹ
Àkọlé àwòrán, Àwọn kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìrin náà kò ní ànfàànì àti wọ bàtà wọn
Àkọlé àwòrán, Àwọn dúkìá táwọn akẹ́kọ̀ọ́bìrin Dapchi fisílẹ̀ di àwòrán ìrántí wọn
Àkọlé àwòrán, Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìrin kan tí wọ́n móríbọ́ ní àwọn kò ní padà sílé ìwé náà mọ́
Àkọlé àwòrán, Kò sẹ́ni tó mọ ibití àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìrin Dapchi wà di àsìkò yìí
Àkọlé àwòrán, Ìjọba Nàijíríà tí táàri baálu lọ sí agbegbe náà lati wá àwọn akẹ́kọbìrín náà wá
Àkọlé àwòrán, Sùgbọn nísín yíì òfífó nile-ìwé àwọn akẹ́kọ náà wà