Ekiti 2018: Àwọn àrímáleèlọ àwòrán láti ibi ìpolongo PDP l'Ékìtì

Ẹ wo aworan awọn to lorukọ ni ẹgbẹ oṣelu PDP bi wọn se peju-pesẹ sibi eto aṣekagba ipolongo PDP fun idibo gomina nilu Ado Ekiti;

Àkọlé àwòrán, Agogo meji abọ ọsan ni eto naa, to yẹ ko ti bẹrẹ ni agogo mẹwa, to bẹrẹ.
Àkọlé àwòrán, Ọjọgbọn Olusola Kolapo Eleka ni oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP
Àkọlé àwòrán, Gbogbo ayika ibudo ipolongo naa lo kun fun ero ti lilọ bibọ ọkọ si ti di iṣoro pẹlu.
Àkọlé àwòrán, Awọn to lorukọ lẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn ti peju-pesẹ sibi eto aṣekagba ipolongo PDP fun idibo gomina nilu Adfo Ekiti
Àkọlé àwòrán, Ilu Ado Ekiti ti n sọ̀kutu-wọ̀wọ̀ fun iwọde ita gbangba fun ipolongo ibo fun oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oselu PDP, Ọmọwe Kọlapọ Olusọla
Àkọlé àwòrán, Awọn olorin pẹlu ko gbẹyin
Àkọlé àwòrán, Ọjọgbọn Olusola Kolapo Eleka ni oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP
Àkọlé àwòrán, Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria nigbakanri, Atiku Abubakar lo lewaju awọn eekan ẹgbẹ oṣelu PDP de ibẹ
Àkọlé àwòrán, ' Ara ọrun' gan bawọn de ibẹ
Àkọlé àwòrán, Aṣekagba ipolongo ibo naa waye ni agbegbe Ojumose roundabout ni ilu Ado-Ekiti
Àkọlé àwòrán, Gbogbo awọn alatilẹyin ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ekiti ati yika ilẹ wa Naijiria lo wa nibẹ